Iṣe Apo 12

12
Inúnibíni sí ìjọ
1LI akoko igbana ni Herodu ọba si nawọ́ rẹ̀ lati pọn awọn kan loju ninu ijọ.
2O si fi idà pa Jakọbu arakunrin Johanu.
3Nigbati o si ri pe, o dùnmọ awọn Ju, o si nawọ́ mu Peteru pẹlu. O si jẹ ìgba ọjọ àiwukàra.
4Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja.
5Nitorina nwọn pa Peteru mọ́ ninu tubu: ṣugbọn ijọ nfi itara gbadura sọdọ Ọlọrun fun u.
Peteru Bọ́ Lẹ́wọ̀n
6Nigbati Herodu iba si mu u jade, li oru na Peteru sùn li arin awọn ọmọ-ogun meji, a fi ẹ̀wọn meji de e, ẹ̀ṣọ́ si wà li ẹnu-ọ̀na, nwọn nṣọ́ tubu na.
7Si wo o, angẹli Oluwa duro tì i, imọlẹ si mọ́ ninu tubu: nigbati o si lù Peteru pẹ́pẹ li ẹgbẹ o ji i, o ni, Dide kánkan. Ẹwọn rẹ̀ si bọ́ silẹ kuro lọwọ rẹ̀.
8Angẹli na si wi fun u pe, Di àmure, ki o si so salubàta rẹ. O si ṣe bẹ̃. O si wi fun u pe, Da aṣọ rẹ bora, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
9On si jade, o ntọ̀ ọ lẹhin; kò si mọ̀ pe otitọ li ohun na ṣe lati ọwọ́ angẹli na wá; ṣugbọn o ṣebi on wà li ojuran.
10Nigbati nwọn kọja iṣọ ikini ati keji, nwọn de ẹnu-ọ̀na ilẹkun irin, ti o lọ si ilu, ti o si tikararẹ̀ ṣí silẹ fun wọn: nigbati nwọn si jade, nwọn nlọ titi li ọ̀na igboro kan; lojukanna angẹli na si fi i silẹ lọ.
11Nigbati oju Peteru si walẹ, o ni, Nigbayi ni mo to mọ̀ nitõtọ pe, Oluwa rán angẹli rẹ̀, o si gbà mi li ọwọ́ Herodu, ati gbogbo ireti awọn enia Ju.
12Nigbati o si rò o, o lọ si ile Maria iya Johanu, ti apele rẹ̀ jẹ Marku; nibiti awọn enia pipọ pejọ si, ti nwọn ngbadura.
13Bi o si ti kàn ilẹkun ẹnu-ọ̀na ọmọbinrin kan ti a npè ni Roda, o wá dahun.
14Nigbati o si ti mọ̀ ohùn Peteru, kò ṣí ilẹkun fun ayọ̀, ṣugbọn o sure wọle, o si sọ pe, Peteru duro li ẹnu-ọ̀na.
15Nwọn si wi fun u pe, Iwọ nṣiwère. Ṣugbọn o tẹnumọ́ ọ gidigidi pe Bẹ̃ni sẹ. Nwọn si wipe, Angẹli rẹ̀ ni.
16Ṣugbọn Peteru nkànkun sibẹ, nigbati nwọn si ṣí ilẹkun, nwọn ri i, ẹnu si yà wọn.
17Ṣugbọn o juwọ́ si wọn pe ki nwọn ki o dakẹ, o si ròhin fun wọn bi Oluwa ti mu on jade kuro ninu tubu. O si wipe, Ẹ lọ isọ nkan wọnyi fun Jakọbu, ati awọn arakunrin. Nigbati o si jade, o lọ si ibomiran.
18Nigbati ilẹ si mọ́, èmimì diẹ kọ li o wà lãrin awọn ọmọ-ogun pe, nibo ni Peteru gbé wà.
19Nigbati Herodu si wá a kiri, ti kò si ri i, o wádi awọn ẹ̀ṣọ, o paṣẹ pe, ki a pa wọn. O si sọkalẹ lati Judea lọ si Kesarea, o si joko nibẹ̀.
Bí Hẹrọdu Ṣe Kú
20Herodu si mbinu gidigidi si awọn ara Tire on Sidoni: ṣugbọn nwọn fi ọkàn kan wá sọdọ rẹ̀, nigbati nwọn si ti tu Blastu iwẹfa ọba loju, nwọn mbẹbẹ fun alafia; nitori lati ilu ọba lọ li a ti mbọ́ ilu wọn.
21Lọjọ afiyesi kan, Herodu gunwà, o joko lori itẹ́, o si nsọ̀rọ fun wọn.
22Awọn enia si hó, wipe, Ohùn ọlọrun ni, kì si iṣe ti enia.
23Lojukanna angẹli Oluwa lù u, nitoriti kò fi ogo fun Ọlọrun: idin si jẹ ẹ, o si kú.
24Ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun gbilẹ, o si bi si i.
25Barnaba on Saulu si pada ti Jerusalemu wá, nigbati nwọn si pari iṣẹ-iranṣẹ wọn, nwọn si mu Johanu wá pẹlu wọn, apele ẹniti ijẹ Marku.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Iṣe Apo 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀