II. Tim 4:9-11

II. Tim 4:9-11 YBCV

Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá. Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia. Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ.