II. Tim 4:9-11
II. Tim 4:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá. Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia. Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ.
Pín
Kà II. Tim 4II. Tim 4:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Sa gbogbo ipá rẹ láti tètè wá sọ́dọ̀ mi. Demasi ti fi mí sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ràn nǹkan ayé yìí. Ó ti lọ sí Tẹsalonika. Kirẹsẹnsi ti lọ sí Galatia. Titu ti lọ sí Dalimatia. Luku nìkan náà ni ó kù lọ́dọ̀ mi. Mú Maku lọ́wọ́ bí o bá ń bọ̀ nítorí ó wúlò fún mi bí iranṣẹ.
Pín
Kà II. Tim 4II. Tim 4:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.
Pín
Kà II. Tim 4