II. Tim 2:22-25

II. Tim 2:22-25 YBCV

Mã sá fun ifẹkufẹ ewe: si mã lepa ododo, igbagbọ́, ifẹ, alafia, pẹlu awọn ti nkepè Oluwa lati inu ọkàn funfun wá. Ṣugbọn ibẽre wère ati alaini ẹkọ́ ninu ni ki o kọ̀, bi o ti mọ̀ pe nwọn ama dá ìja silẹ. Iranṣẹ Oluwa kò si gbọdọ jà; bikoṣe ki o jẹ ẹni pẹlẹ si enia gbogbo, ẹniti o le kọ́ni, onisũru, Ẹniti yio mã kọ́ awọn aṣodi pẹlu iwa tutu; boya Ọlọrun le fun wọn ni ironupiwada si imọ otitọ