TIMOTI KEJI 2:22-25

TIMOTI KEJI 2:22-25 YCE

Yẹra fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́. Máa lépa òdodo ati ìṣòtítọ́, ìfẹ́, ati alaafia, pẹlu àwọn tí ó ń képe Oluwa pẹlu ọkàn mímọ́. Má bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ati ọ̀rọ̀ òpè. Ranti pé ìjà ni wọ́n ń dá sílẹ̀. Iranṣẹ Oluwa kò sì gbọdọ̀ jà. Ṣugbọn ó níláti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo eniyan, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà. Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́