II. Sam 23:1-23

II. Sam 23:1-23 YBCV

WỌNYI si li ọ̀rọ ikẹhin Dafidi. Dafidi ọmọ Jesse, ani ọkunrin ti a ti gbega, ẹni-ami-ororo Ọlọrun Jakobu, ati olorin didùn Israeli wi pe, Ẹmi Oluwa sọ ọ̀rọ nipa mi, ọ̀rọ rẹ̀ si mbẹ li ahọn mi. Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun. Yio si dabi imọlẹ owurọ nigbati õrun ba là, owurọ ti kò ni ikũku, nigbati koriko tutu ba hù lati ilẹ wa nipa itanṣan lẹhin òjo. Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà? Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Beliali yio dabi ẹgún ẹ̀wọn ti a ṣatì, nitoripe a kò le fi ọwọ́ kó wọn. Ṣugbọn ọkunrin ti yio tọ́ wọn yio fi irin ati ọpa ọ̀kọ sagbàra yi ara rẹ̀ ka: nwọn o si jona lulu nibi kanna. Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin alagbara ti Dafidi ni: ẹniti o joko ni ibujoko Takmoni ni olori awọn balogun, on si ni Adino Esniti ti o pa ẹgbẹ̀rin enia lẹ̃kan. Ẹniti o tẹ̀le e ni Eleasari ọmọ Dodo ara Ahohi, ọkan ninu awọn alagbara ọkunrin mẹta ti o wà pẹlu Dafidi, nigbati nwọn pe awọn Filistini ni ijà, awọn ti o kó ara wọn jọ si ibẹ lati jà, awọn ọmọkunrin Israeli si ti lọ kuro: On si dide, o si kọlù awọn Filistini titi ọwọ́ fi kún u, ọwọ́ rẹ̀ si lẹ̀ mọ idà: Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla li ọjọ na; awọn enia si yipada lẹhin rẹ̀ lati ko ikogun. Ẹniti o tẹ̀le e ni Samma ọmọ Agee ará Harari. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ lati piyẹ, oko kan si wà nibẹ ti o kún fun ẹwẹ: awọn enia si sa kuro niwaju awọn Filistini. O si duro lagbedemeji ilẹ na, o si gbà a silẹ, o si pa awọn Filistini: Oluwa si ṣe igbala nla kan. Awọn mẹta ninu ọgbọ̀n olori si sọkalẹ, nwọn si tọ Dafidi wá li akoko ikore ninu iho Adullamu: ọ̀wọ́ awọn Filistini si do ni afonifoji Refaimu. Dafidi si wà ninu odi, ibudo awọn Filistini si wà ni Betlehemu nigbana. Dafidi si k'ongbẹ, o wi bayi pe, Tani yio fun mi mu ninu omi kanga ti mbẹ ni Betlehemu, eyi ti o wà ni ihà ẹnu-bodè? Awọn ọkunrin alagbara mẹta si la ogun awọn Filistini lọ, nwọn si fa omi lati inu kanga Betlehemu wá, eyi ti o wà ni iha ẹnu-bode, nwọn si mu tọ Dafidi wá: on kò si fẹ mu ninu rẹ̀, ṣugbọn o tú u silẹ fun Oluwa. On si wipe, Ki a ma ri, Oluwa, ti emi o fi ṣe eyi; ṣe eyi li ẹ̀jẹ awọn ọkunrin ti o lọ ti awọn ti ẹmi wọn li ọwọ́? nitorina on kò si fẹ mu u. Nkan wọnyi li awọn ọkunrin alagbara mẹtẹta yi ṣe. Abiṣai, arakunrin Joabu, ọmọ Seruia, on na ni pataki ninu awọn mẹta. On li o si gbe ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia, o si pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹtẹta. Ọlọlajulọ li on iṣe ninu awọn mẹtẹta: o si jẹ olori fun wọn: ṣugbọn on kò to awọn mẹta iṣaju. Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, on pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; o sọkalẹ pẹlu o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno. O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o tó wò: ara Egipti na si ni ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn on si sọkalẹ tọ̀ ọ lọ, ton ti ọ̀pá li ọwọ́, o si gba ọ̀kọ na lọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ tirẹ̀ pa a. Nkan wọnyi ni Benaia ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn ọkunrin alagbara mẹta nì. Ninu awọn ọgbọ̀n na, on ṣe ọlọlajulọ, ṣugbọn on kò to awọn mẹta ti iṣaju. Dafidi si fi i ṣe igbimọ̀ rẹ̀.