II. Sam 23:1-23

II. Sam 23:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli: “Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi. Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀, Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé, ‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba, tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu, ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu; ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun, nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo, majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀. Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi. Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrun dàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù, kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú. Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀, láti fi wọ́n jóná patapata.” Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn. Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa. Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu. Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.” Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA. Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe. Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn. Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á. Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”. Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

II. Sam 23:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

WỌNYI si li ọ̀rọ ikẹhin Dafidi. Dafidi ọmọ Jesse, ani ọkunrin ti a ti gbega, ẹni-ami-ororo Ọlọrun Jakobu, ati olorin didùn Israeli wi pe, Ẹmi Oluwa sọ ọ̀rọ nipa mi, ọ̀rọ rẹ̀ si mbẹ li ahọn mi. Ọlọrun Israeli ní, Apata Israeli sọ fun mi pe, Ẹnikan ti nṣe alakoso enia lododo, ti nṣakoso ni ibẹru Ọlọrun. Yio si dabi imọlẹ owurọ nigbati õrun ba là, owurọ ti kò ni ikũku, nigbati koriko tutu ba hù lati ilẹ wa nipa itanṣan lẹhin òjo. Lõtọ ile mi kò ri bẹ niwaju Ọlọrun, ṣugbọn o ti ba mi da majẹmu ainipẹkun, ti a tunṣe ninu ohun gbogbo, ti a si pamọ: nitoripe gbogbo eyi ni igbala mi, ati gbogbo ifẹ mi, ile mi kò le ṣe ki o ma dagbà? Ṣugbọn gbogbo awọn ọmọ Beliali yio dabi ẹgún ẹ̀wọn ti a ṣatì, nitoripe a kò le fi ọwọ́ kó wọn. Ṣugbọn ọkunrin ti yio tọ́ wọn yio fi irin ati ọpa ọ̀kọ sagbàra yi ara rẹ̀ ka: nwọn o si jona lulu nibi kanna. Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin alagbara ti Dafidi ni: ẹniti o joko ni ibujoko Takmoni ni olori awọn balogun, on si ni Adino Esniti ti o pa ẹgbẹ̀rin enia lẹ̃kan. Ẹniti o tẹ̀le e ni Eleasari ọmọ Dodo ara Ahohi, ọkan ninu awọn alagbara ọkunrin mẹta ti o wà pẹlu Dafidi, nigbati nwọn pe awọn Filistini ni ijà, awọn ti o kó ara wọn jọ si ibẹ lati jà, awọn ọmọkunrin Israeli si ti lọ kuro: On si dide, o si kọlù awọn Filistini titi ọwọ́ fi kún u, ọwọ́ rẹ̀ si lẹ̀ mọ idà: Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla li ọjọ na; awọn enia si yipada lẹhin rẹ̀ lati ko ikogun. Ẹniti o tẹ̀le e ni Samma ọmọ Agee ará Harari. Awọn Filistini si ko ara wọn jọ lati piyẹ, oko kan si wà nibẹ ti o kún fun ẹwẹ: awọn enia si sa kuro niwaju awọn Filistini. O si duro lagbedemeji ilẹ na, o si gbà a silẹ, o si pa awọn Filistini: Oluwa si ṣe igbala nla kan. Awọn mẹta ninu ọgbọ̀n olori si sọkalẹ, nwọn si tọ Dafidi wá li akoko ikore ninu iho Adullamu: ọ̀wọ́ awọn Filistini si do ni afonifoji Refaimu. Dafidi si wà ninu odi, ibudo awọn Filistini si wà ni Betlehemu nigbana. Dafidi si k'ongbẹ, o wi bayi pe, Tani yio fun mi mu ninu omi kanga ti mbẹ ni Betlehemu, eyi ti o wà ni ihà ẹnu-bodè? Awọn ọkunrin alagbara mẹta si la ogun awọn Filistini lọ, nwọn si fa omi lati inu kanga Betlehemu wá, eyi ti o wà ni iha ẹnu-bode, nwọn si mu tọ Dafidi wá: on kò si fẹ mu ninu rẹ̀, ṣugbọn o tú u silẹ fun Oluwa. On si wipe, Ki a ma ri, Oluwa, ti emi o fi ṣe eyi; ṣe eyi li ẹ̀jẹ awọn ọkunrin ti o lọ ti awọn ti ẹmi wọn li ọwọ́? nitorina on kò si fẹ mu u. Nkan wọnyi li awọn ọkunrin alagbara mẹtẹta yi ṣe. Abiṣai, arakunrin Joabu, ọmọ Seruia, on na ni pataki ninu awọn mẹta. On li o si gbe ọ̀kọ rẹ̀ soke si ọ̃dunrun enia, o si pa wọn, o si ni orukọ ninu awọn mẹtẹta. Ọlọlajulọ li on iṣe ninu awọn mẹtẹta: o si jẹ olori fun wọn: ṣugbọn on kò to awọn mẹta iṣaju. Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkunrin kan ti Kabseeli, ẹniti o pọ̀ ni iṣe agbara, on pa awọn ọmọ Arieli meji ti Moabu; o sọkalẹ pẹlu o si pa kiniun kan ninu iho lakoko sno. O si pa ara Egipti kan, ọkunrin ti o tó wò: ara Egipti na si ni ọ̀kọ kan li ọwọ́ rẹ̀: ṣugbọn on si sọkalẹ tọ̀ ọ lọ, ton ti ọ̀pá li ọwọ́, o si gba ọ̀kọ na lọwọ ara Egipti na, o si fi ọ̀kọ tirẹ̀ pa a. Nkan wọnyi ni Benaia ọmọ Jehoiada ṣe, o si li orukọ ninu awọn ọkunrin alagbara mẹta nì. Ninu awọn ọgbọ̀n na, on ṣe ọlọlajulọ, ṣugbọn on kò to awọn mẹta ti iṣaju. Dafidi si fi i ṣe igbimọ̀ rẹ̀.

II. Sam 23:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi nìyí; àní, ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Dafidi, ọmọ Jese, tí a gbé ga ní Israẹli, ẹni àmì òróró Ọlọrun Jakọbu, olórin dídùn ní Israẹli: “Ẹ̀mí OLUWA ń gba ẹnu mi sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní ẹnu mi. Ọlọrun Israẹli ti sọ̀rọ̀, Àpáta Israẹli ti wí fún mi pé, ‘Ẹni yòówù tí ó bá fi òtítọ́ jọba, tí ó ṣe àkóso pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun, a máa tàn sí wọn bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, bí oòrùn tí ó ń ràn ní òwúrọ̀ kutukutu, ní ọjọ́ tí kò sí ìkùukùu; ó dàbí òjò tí ń mú kí koríko hù jáde láti inú ilẹ̀.’ “Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún arọmọdọmọ mi níwájú Ọlọrun, nítorí pé, ó ti bá mi dá majẹmu ayérayé nípa ohun gbogbo, majẹmu tí kò lè yipada, ati ìlérí tí kò ní yẹ̀. Yóo ṣe ohun tí mo fẹ́ fún mi. Yóo ràn mí lọ́wọ́, yóo fún mi ní ìfẹ́ ọkàn mi. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò mọ Ọlọrun dàbí igi ẹ̀gún tí a gbé sọnù, kò sí ẹni tí ó lè fi ọwọ́ lásán gbá wọn mú. Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀, láti fi wọ́n jóná patapata.” Orúkọ àwọn ọmọ ogun Dafidi tí wọ́n jẹ́ akọni ati akikanju nìwọ̀nyí: Ekinni ni, Joṣebu-Baṣebeti, ará Takimoni, òun ni olórí ninu “Àwọn Akọni Mẹta,” ó fi ọ̀kọ̀ bá ẹgbẹrin (800) eniyan jà, ó sì pa gbogbo wọn ninu ogun kan ṣoṣo. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn. Ṣugbọn Eleasari dúró gbọningbọnin, ó sì bá àwọn ará Filistia jà títí tí ọwọ́ rẹ̀ fi wo koko mọ́ idà rẹ̀, tí kò sì le jù ú sílẹ̀ mọ́. OLUWA ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Lẹ́yìn tí ogun náà parí ni àwọn ọmọ ogun Israẹli tó pada sí ibi tí Eleasari wà, tí wọ́n lọ kó àwọn ohun ìjà tí ó wà lára àwọn tí ogun pa. Ẹnìkẹta ninu àwọn akọni náà ni Ṣama, ọmọ Agee, ará Harari. Ní àkókò kan, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ sí Lehi, níbi tí oko ewébẹ̀ kan wà. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sá fún àwọn ará Filistia, ṣugbọn Ṣama dúró gbọningbọnin ní ojú ogun. Ó jà kíkankíkan, ó sì pa àwọn ará Filistia. OLUWA sì ja àjàṣẹ́gun ńlá ní ọjọ́ náà. Nígbà tí àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè súnmọ́ tòsí, mẹta ninu àwọn ọgbọ̀n akọni náà lọ sí inú ihò àpáta tí ó wà ní Adulamu, níbi tí Dafidi wà nígbà náà, nígbà tí ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini pàgọ́ wọn sí àfonífojì Refaimu. Dafidi wà ní orí òkè kan tí wọ́n mọ odi yípo, ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun Filistini kan ti gba Bẹtilẹhẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.” Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA. Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe. Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn. Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ará Kabiseeli, náà tún jẹ́ akọni ọmọ ogun, ọpọlọpọ nǹkan ńláńlá ni ó fi ìgboyà ṣe. Ó pa àwọn akikanju ọmọ ogun ará Moabu meji ní àkókò kan. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí yìnyín bọ́ sílẹ̀, ó wọ inú ihò kan lọ, ó sì pa kinniun kan sibẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni, ó pa ọkunrin ará Ijipti kan tí ó ṣígbọnlẹ̀, tí ó sì dira ogun tòun tọ̀kọ̀. Kùmọ̀ lásán ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ tí ó fi dojú kọ ọ́, ó já ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ ọmọ ogun ará Ijipti yìí gbà, ó sì fi pa á. Àwọn nǹkan akikanju ti Bẹnaya ṣe nìwọ̀nyí, ó sì ní òkìkí, yàtọ̀ sí ti “Àwọn Akọni Mẹta”. Akọni ni láàrin “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni”, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” ti àkọ́kọ́, òun ni Dafidi sì fi ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.

II. Sam 23:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni ààmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé: “Ẹ̀mí OLúWA sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi. Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé: ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ “Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká; wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.” Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò. Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; OLúWA sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun. Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili: àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini. Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini OLúWA sì ṣe ìgbàlà ńlá. Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu: ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí Àfonífojì Refaimu. Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà. Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.” Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá: òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún OLúWA. Òun sì wí pé, “Kí a má rí, OLúWA, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un. Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe. Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: ó sì jẹ́ olórí fún wọn: ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú. Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì. Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò: ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á. Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà. Nínú àwọn ọgbọ̀n (30) náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.