Dafidi ọba si ranṣẹ si Sadoku, ati si Abiatari awọn alufa pe, Sọ fun awọn agbà Juda, pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá si ile rẹ̀? ọ̀rọ gbogbo Israeli si ti de ọdọ ọba ani ni ile rẹ̀.
Ẹnyin li ará mi, ẹnyin li egungun mi, ati ẹran ara mi: ẹ̃si ti ṣe ti ẹnyin fi kẹhìn lati mu ọba pada wá?
Ki ẹnyin ki o si wi fun Amasa pe, Egungun ati ẹran ara mi ki iwọ iṣe bi? ki Ọlọrun ki o ṣe bẹ̃ si mi ati ju bẹ̃ lọ pẹlu, bi iwọ kò ba ṣe olori ogun niwaju mi titi, ni ipò Joabu.
On si yi ọkàn gbogbo awọn ọkunrin Juda, ani bi ọkàn enia kan; nwọn si ranṣẹ si ọba, pe, Iwọ pada ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ.
Ọba si pada, o si wá si odo Jordani. Juda si wá si Gilgali, lati lọ ipade ọba, ati lati mu ọba kọja odo Jordani.
Ṣimei ọmọ Gera, ara Benjamini ti Bahurimu, o yara o si ba awọn ọkunrin Juda sọkalẹ lati pade Dafidi ọba.
Ẹgbẹrun ọmọkunrin si wà lọdọ rẹ̀ ninu awọn ọmọkunrin Benjamini, Siba iranṣẹ ile Saulu, ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ mẹ̃dogun ati ogún iranṣẹ si pẹlu rẹ̀; nwọn si goke odo Jordani ṣaju ọba.
Ọkọ̀ èro kan ti rekọja lati kó awọn enia ile ọba si oke, ati lati ṣe eyiti o tọ li oju rẹ̀. Ṣimei ọmọ Gera wolẹ, o si dojubolẹ niwaju ọba, bi o ti goke odo Jordani.
O si wi fun ọba pe, Ki oluwa mi ki o máṣe ka ẹ̀ṣẹ si mi li ọrùn, má si ṣe ranti afojudi ti iranṣẹ rẹ ṣe li ọjọ ti oluwa mi ọba jade ni Jerusalemu, ki ọba ki o má si fi si inu.
Nitoripe iranṣẹ rẹ mọ̀ pe on ti ṣẹ̀; si wõ, ni gbogbo idile Josefu emi li o kọ́ wá loni lati sọkalẹ wá pade oluwa mi ọba.
Ṣugbọn Abiṣai ọmọ Seruia dahùn o si wipe, Kò ha tọ́ ki a pa Ṣimei nitori eyi? nitoripe on ti bú ẹni-àmi-ororo Oluwa.
Dafidi si wipe, Ki li o wà lãrin emi ati ẹnyin, ẹnyin ọmọ Seruia, ti ẹ fi di ọta si mi loni? a ha le pa enia kan loni ni Israeli? o le ṣe pe emi kò mọ̀ pe, loni emi li ọba Israeli?
Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ kì yio kú. Ọba si bura fun u.
Mefiboṣeti ọmọ Saulu si sọkalẹ lati wá pade ọba, kò wẹ ẹsẹ rẹ̀, kò si fá irungbọ̀n rẹ̀, bẹ̃ni kò si fọ aṣọ rẹ̀ lati ọjọ ti ọba ti jade titi o fi di ọjọ ti o fi pada li alafia.
O si ṣe, nigbati on si wá si Jerusalemu lati pade ọba, ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ kò fi ba mi lọ, Mefiboṣeti?
On si dahùn wipe, Oluwa mi, ọba, iranṣẹ mi li o tàn mi jẹ; nitoriti iranṣẹ rẹ ti wipe, Emi o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, emi o gùn u, emi o si tọ̀ ọba lọ, nitoriti iranṣẹ rẹ yarọ.
O si sọ̀rọ ibajẹ si iranṣẹ rẹ, fun oluwa mi ọba, ṣugbọn bi angeli Ọlọrun li oluwa mi ọba ri: nitorina ṣe eyi ti o dara loju rẹ.
Nitoripe gbogbo ile baba mi bi okú enia ni nwọn sa ri niwaju oluwa mi ọba: iwọ si fi ipò fun iranṣẹ rẹ larin awọn ti o njẹun ni ibi onjẹ rẹ. Nitorina are kili emi ni ti emi o fi ma ke pe ọba sibẹ.
Ọba si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nsọ ọràn rẹ siwaju mọ? emi sa ti wipe, Ki iwọ ati Siba pin ilẹ na.
Mefiboṣeti si wi fun ọba pe, Si jẹ ki o mu gbogbo rẹ̀, bi oluwa mi ọba ba ti pada bọ̀ wá ile rẹ̀ li alafia.
Barsillai ara Gileadi si sọkalẹ lati Rogelimu wá, o si ba ọba goke odo Jordani, lati ṣe ikẹ́ rẹ̀ si ikọja odo Jordani.
Barsillai si jẹ arugbo ọkunrin gidigidi, ẹni ogbó ọgọrin ọdun si ni: o si pese ohun jijẹ fun ọba nigbati o ti wà ni Mahanaimu; nitoripe ọkunrin ọlọla li on iṣe.
Ọba si wi fun Barsillai pe, Iwọ wá ba mi goke odo, emi o si ma bọ́ ọ ni Jerusalemu.
Barsillai si wi fun ọba pe, Ọjọ melo ni ọdun ẹmi mi kù, ti emi o fi ba ọba goke lọ si Jerusalemu?
Ẹni ogbó ọgọrin ọdun sa li emi loni: emi le mọ̀ iyatọ ninu rere ati buburu? iranṣẹ rẹ le mọ̀ adùn ohun ti emi njẹ tabi ohun ti emi nmu bi? emi tun le mọ̀ adùn ohùn awọn ọkunrin ti nkọrin, ati awọn obinrin ti nkọrin bi? njẹ nitori kili iranṣẹ rẹ yio ṣe jẹ́ iyọnu sibẹ fun oluwa mi ọba?
Iranṣẹ rẹ yio si sin ọba lọ diẹ goke odo Jordani; ẽsi ṣe ti ọba yio fi san ẹsan yi fun mi?
Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ pada, emi o si kú ni ilu mi, a o si sin mi ni iboji baba ati iya mi. Si wo Kimhamu iranṣẹ rẹ, yio ba oluwa mi ọba goke; iwọ o si ṣe ohun ti o ba tọ li oju rẹ fun u.
Ọba si dahùn wipe, Kimhamu yio ba mi goke, emi o si ṣe eyi ti o tọ loju rẹ fun u; ohunkohun ti iwọ ba si bere lọwọ mi, emi o ṣe fun ọ.
Gbogbo awọn enia si goke odo Jordani. Ọba si goke; ọba si fi ẹnu kò Barsillai li ẹnu, o si sure fun u; on si pada si ile rẹ̀.
Ọba si nlọ si Gilgali, Kimhamu si mba a lọ, gbogbo awọn enia Juda si nṣe ikẹ ọba, ati ãbọ awọn enia Israeli.
Si wõ, gbogbo awọn ọkunrin Israeli si tọ ọba wá, nwọn si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti awọn arakunrin wa awọn ọkunrin Juda fi ji ọ kuro, ti nwọn si fi mu ọba ati awọn ara ile rẹ̀ goke odo Jordani, ati gbogbo awọn enia Dafidi pẹlu rẹ̀.
Gbogbo ọkunrin Juda si da awọn ọkunrin Israeli li ohùn pe, Nitoripe ọba bá wa tan ni; ẽṣe ti ẹnyin fi binu nitori ọran yi? awa jẹ ninu onjẹ ọba rara bi? tabi o fi ẹ̀bun kan fun wa bi?
Awọn ọkunrin Israeli si da awọn ọkunrin Juda li ohùn pe, Awa ni ipa mẹwa ninu ọba, awa si ni ninu Dafidi jù nyin lọ, ẽṣe ti ẹnyin kò fi kà wa si, ti ìmọ wa kò fi ṣaju lati mu ọba wa pada? ọ̀rọ awọn ọkunrin Juda si le jù ọ̀rọ awọn ọkunrin Israeli lọ.