SAMUẸLI KEJI 19:11-43

SAMUẸLI KEJI 19:11-43 YCE

Ìròyìn ohun tí àwọn eniyan Israẹli ń wí kan Dafidi ọba lára. Dafidi ọba ranṣẹ sí àwọn alufaa mejeeji: Sadoku, ati Abiatari, láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà Juda pé, “Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀? Ṣebí ìbátan ọba ni yín, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni yín? Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀.” Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ yìí, mú kí àwọn eniyan Juda fara mọ́ ọn, wọ́n sì ranṣẹ sí i pé kí ó pada pẹlu gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani. Ní àkókò yìí kan náà, Ṣimei, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini, láti ìlú Bahurimu, sáré lọ sí odò Jọdani láti pàdé Dafidi ọba pẹlu àwọn eniyan Juda. Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀. Wọ́n rékọjá odò sí òdìkejì, láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn yóo sin ìdílé ọba kọjá odò, ati láti ṣe ohunkohun tí ọba bá fẹ́. Bí ọba ti múra láti kọjá odò náà, Ṣimei wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó ní, “Kabiyesi, jọ̀wọ́ má dá mi lẹ́bi, má sì ranti àṣìṣe tí mo ṣe ní ọjọ́ tí o kúrò ní Jerusalẹmu, jọ̀wọ́ gbàgbé rẹ̀. Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀; Ìdí nìyí, tí ó fi jẹ́ pé èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́ wá pàdé rẹ lónìí, ninu gbogbo ìdílé Josẹfu.” Abiṣai ọmọ Seruaya dáhùn pé, “Pípa ni ó yẹ kí á pa Ṣimei nítorí pé ó ṣépè lé ẹni tí OLUWA fi òróró yàn ní ọba.” Ṣugbọn Dafidi dá Abiṣai ati Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lóhùn pé, “Kí ló kàn yín ninu ọ̀rọ̀ yìí? Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya, tí ẹ̀ ń ṣe bí ọ̀tá sí mi? Èmi ni ọba Israẹli lónìí, ẹnìkan kò sì ní pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” Ó bá dá Ṣimei lóhùn, ó ní, “Mo búra fún ọ pé ẹnikẹ́ni kò ní pa ọ́.” Lẹ́yìn náà, Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, wá pàdé ọba. Láti ìgbà tí ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, títí tí ó fi pada dé ní alaafia, Mẹfiboṣẹti kò fọ ẹsẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gé irùngbọ̀n rẹ̀, tabi kí ó fọ aṣọ rẹ̀. Nígbà tí Mẹfiboṣẹti ti Jerusalẹmu dé láti pàdé ọba, ọba bi í pé, “Mẹfiboṣẹti, kí ló dé tí o kò fi bá mi lọ?” Mẹfiboṣẹti dáhùn pé, “Kabiyesi, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, arọ ni mí. Mo sọ fún iranṣẹ mi pé kí ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì, kí n lè gùn ún tẹ̀lé ọ, ṣugbọn ó hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi. Ó lọ pa irọ́ mọ́ mi lọ́dọ̀ ọba. Ṣugbọn bí angẹli Ọlọrun ni oluwa mi, ọba rí; nítorí náà, ṣe ohun tí ó bá tọ́ sí mi ní ojú rẹ. Gbogbo ìdílé baba mi pátá ni ó yẹ kí o pa, ṣugbọn o gbà mí láàyè; o sì fún mi ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹun níbi tabili rẹ. Kò yẹ mí rárá, láti tún bèèrè nǹkankan mọ́ lọ́wọ́ kabiyesi.” Ọba dá a lóhùn pé, “Má wulẹ̀ tún sọ nǹkankan mọ́, mo ti pinnu pé ìwọ ati Siba ni yóo pín gbogbo ogun Saulu.” Mẹfiboṣẹti bá dáhùn pé, “Jẹ́ kí Siba máa mú gbogbo rẹ̀, kìkì pé kabiyesi pada dé ilé ní alaafia ti tó fún mi.” Basilai ará Gileadi náà wá láti Rogelimu. Ó bá ọba dé odò Jọdani láti sìn ín kọjá odò náà. Basilai ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọrin ọdún ni. Ó tọ́jú nǹkan jíjẹ fún ọba nígbà tí ó fi wà ní Mahanaimu, nítorí pé ọlọ́rọ̀ ni. Ọba wí fún un pé, “Bá mi kálọ sí Jerusalẹmu, n óo sì tọ́jú rẹ dáradára.” Ṣugbọn Basilai dáhùn pé, “Ọjọ́ tí ó kù fún mi láyé kò pọ̀ mọ́, kí ni n óo tún máa bá kabiyesi lọ sí Jerusalẹmu fún? Mo ti di ẹni ọgọrin ọdún, kò sì sí ohunkohun tí ó tún wù mí mọ́. Oúnjẹ ati ohun mímu kò dùn lẹ́nu mi mọ́. Bí àwọn akọrin ń kọrin, n kò lè gbọ́ orin wọn mọ́. Wahala lásán ni n óo lọ kó bá oluwa mi, ọba. Irú anfaani ńlá báyìí kò tọ́ sí mi láti ọ̀dọ̀ ọba, nítorí náà, n óo bá ọba gun òkè odò Jọdani, n óo sì bá ọ lọ sí iwájú díẹ̀ ni. Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.” Ọba dáhùn pé, “N óo máa mú Kimhamu lọ, ohunkohun tí ó bá sì bèèrè, ni n óo ṣe fún un.” Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn ará ilẹ̀ Juda, ati ìdajì àwọn ọmọ Israẹli ti sin ọba kọjá odò, ọba lọ sí Giligali, Kimhamu sì bá a lọ. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?” Àwọn eniyan Juda bá dáhùn pé, “Ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ọ̀kan náà ni àwa ati ọba. Kí ló dé tí èyí fi níláti bà yín ninu jẹ́? Kì í ṣá ṣe pé òun ni ó ń bọ́ wa, a kò sì gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “Ìlọ́po mẹ́wàá ẹ̀tọ́ tí ẹ ní sí ọba ni àwa ní, kì báà tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan náà ni yín. Kí ló dé tí ẹ fi fi ojú tẹmbẹlu wa? Ẹ má gbàgbé pé àwa ni a dábàá ati mú ọba pada sílé.” Ṣugbọn ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Juda le ju ti àwọn ará ilẹ̀ Israẹli lọ.