II. Sam 19:1-10

II. Sam 19:1-10 YBCV

A si rò fun Joabu pe, Wõ, ọba nsọkun, o si ngbawẹ fun Absalomu. Iṣẹgun ijọ na si di awẹ̀ fun gbogbo awọn enia na, nitori awọn enia na gbọ́ ni ijọ na bi inu ọba ti bajẹ nitori ọmọ rẹ̀. Awọn enia na si yọ́ lọ si ilu ni ijọ na gẹgẹ bi awọn enia ti a dojuti a ma yọ́ lọ nigbati nwọn nsá loju ijà. Ọba si bo oju rẹ̀, ọba si kigbe li ohùn rara pe, A! ọmọ mi Absalomu, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi! Joabu si wọ inu ile tọ ọba lọ, o si wipe, Iwọ dojuti gbogbo awọn iranṣẹ rẹ loni, awọn ti o gbà ẹmi rẹ là loni, ati ẹmi awọn ọmọkunrin rẹ, ati ti awọn ọmọbinrin rẹ, ati ẹmi awọn aya rẹ, ati ẹmi awọn obinrin rẹ. Nitoripe iwọ fẹ awọn ọta rẹ, iwọ si korira awọn ọrẹ rẹ. Nitoriti iwọ wi loni pe, Iwọ kò nani awọn ọmọ ọba, tabi awọn iranṣẹ: emi si ri loni pe, ibaṣepe Absalomu wà lãye, ki gbogbo wa si kú loni, njẹ iba dùnmọ ọ gidigidi. Si dide nisisiyi, lọ, ki o si sọ̀rọ itùnú fun awọn iranṣẹ rẹ: nitoripe emi fi Oluwa bura, bi iwọ kò ba lọ, ẹnikan kì yio ba ọ duro li alẹ yi: ati eyini yio si buru fun ọ jù gbogbo ibi ti oju rẹ ti nri lati igbà ewe rẹ wá titi o fi di isisiyi. Ọba si dide, o si joko li ẹnu ọ̀na. Nwọn si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Wõ, ọba joko li ẹnu ọ̀na. Gbogbo enia si wá si iwaju ọba: nitoripe, Israeli ti sa, olukuluku si àgọ́ rẹ̀. Gbogbo awọn enia na si mba ara wọn jà ninu gbogbo ẹya Israeli, pe, Ọba ti gbà wa là lọwọ awọn ọta wa, o si ti gbà wa kuro lọwọ awọn Filistini; on si wa sa kuro ni ilu nitori Absalomu. Absalomu, ti awa fi jọba lori wa si kú li ogun: njẹ ẽṣe ti ẹnyin fi dakẹ ti ẹnyin kò si sọ̀rọ kan lati mu ọba pada wá?