Àwọn kan lọ sọ fún Joabu pé, ọba ń sọkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ Absalomu. Nítorí náà, ìṣẹ́gun ọjọ́ náà pada di ìbànújẹ́ fún gbogbo àwọn eniyan; nítorí wọ́n gbọ́ pé ọba ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun náà yọ́ wọ ìlú jẹ́ẹ́, bí ẹni pé wọ́n sá lójú ogun, tí ìtìjú sì mú wọn. Ọba dọwọ́ bojú, ó ń sọkún, ó sì ń kígbe sókè pé, “Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi!”
Joabu bá wọlé tọ ọba lọ, ó wí fún un pé, “O ti dójúti àwọn ọmọ ogun rẹ lónìí, àwọn tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ là, ati ẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ, ati ti àwọn aya rẹ, ati àwọn obinrin rẹ; nítorí pé o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. O ti fihàn gbangba pé, àwọn ọ̀gágun ati ọmọ ogun rẹ kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ. Mo ti rí i gbangba lónìí pé, ìbá dùn mọ́ ọ ninu, bí gbogbo wa tilẹ̀ kú, tí Absalomu sì wà láàyè. Yára dìde, kí o lọ tu àwọn ọmọ ogun ninu; nítorí pé mo fi OLUWA búra pé, bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní ku ẹnìkan ninu wọn pẹlu rẹ ní òwúrọ̀ ọ̀la. Èyí yóo wá burú ju gbogbo ibi tí ó ti bá ọ láti ìgbà èwe rẹ títí di òní lọ.” Ọba bá dìde, ó lọ jókòó lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ibodè. Àwọn eniyan rẹ̀ gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, gbogbo wọn bá wá rọ̀gbà yí i ká.
Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá, olukuluku ti pada sí ilé rẹ̀. Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu. A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.”