II. Sam 15:23-37

II. Sam 15:23-37 YBCV

Gbogbo ilu na si fi ohùn rara sọkun, gbogbo enia si rekọja; ọba si rekọja odo Kidroni, gbogbo awọn enia na si rekọja, si ihà ọ̀na iju. Si wõ, Sadoku pẹlu ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o wà lọdọ rẹ̀ si nru apoti-ẹri Ọlọrun: nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na kalẹ; Abiatari si goke, titi gbogbo awọn enia si fi dẹkun ati ma kọja lati ilu wá. Ọba si wi fun Sadoku pe, Si tun gbe apoti-ẹri Ọlọrun na pada si ilu: bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ Oluwa, yio si tun mu mi pada wá, yio si fi apoti-ẹri na hàn mi ati ibugbe rẹ̀. Ṣugbọn bi on ba si wi pe, Emi kò ni inu didùn si ọ; wõ, emi niyi, jẹ ki on ki o ṣe si mi gẹgẹ bi o ti tọ́ li oju rẹ̀. Ọba si wi fun Sadoku alufa pe, Iwọ kọ́ ariran? pada si ilu li alafia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ, Ahimaasi ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari. Wõ, emi o duro ni pẹtẹlẹ iju nì, titi ọ̀rọ o fi ti ọdọ rẹ wá lati sọ fun mi. Sadoku ati Abiatari si gbe apoti-ẹri Ọlọrun pada si Jerusalemu: nwọn si gbe ibẹ̀. Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rẹ̀, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀, olukuluku ọkunrin si bò ori rẹ̀, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ. Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan. O si ṣe, Dafidi de ori oke, nibiti o gbe wolẹ̀ sin Ọlọrun, si wõ, Huṣai ara Arki nì si wá lati pade rẹ̀ ti on ti aṣọ rẹ̀ yiya, ati erupẹ, li ori rẹ̀. Dafidi si wi fun u pe, bi iwọ ba bá mi kọja, iwọ o si jẹ idiwọ fun mi. Bi iwọ ba si pada si ilu, ti o si wi fun Absalomu pe, Emi o ṣe iranṣẹ rẹ, ọba, gẹgẹ bi emi ti ṣe iranṣẹ baba rẹ nigba atijọ, bẹ̃li emi o si jẹ iranṣẹ rẹ nisisiyi: ki iwọ ki o si bà ìmọ Ahitofeli jẹ. Ṣe Sadoku ati Abiatari awọn alufa wà nibẹ pẹlu rẹ? yio si ṣe, ohunkohun ti iwọ ba gbọ́ lati ile ọba wá, iwọ o si sọ fun Sadoku ati Abiatari awọn alufa. Wõ, nwọn si ni ọmọ wọn mejeji nibẹ pẹlu wọn, Ahimaasi ọmọ Sadoku, ati Jonatani ọmọ Abiatari; lati ọwọ́ wọn li ẹnyin o si rán ohunkohun ti ẹnyin ba gbọ́ si mi. Huṣai ọrẹ Dafidi si wá si ilu, Absalomu si wá si Jerusalemu.