II. Sam 15:23-37

II. Sam 15:23-37 Bibeli Mimọ (YBCV)

Gbogbo ilu na si fi ohùn rara sọkun, gbogbo enia si rekọja; ọba si rekọja odo Kidroni, gbogbo awọn enia na si rekọja, si ihà ọ̀na iju. Si wõ, Sadoku pẹlu ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti o wà lọdọ rẹ̀ si nru apoti-ẹri Ọlọrun: nwọn si gbe apoti-ẹri Ọlọrun na kalẹ; Abiatari si goke, titi gbogbo awọn enia si fi dẹkun ati ma kọja lati ilu wá. Ọba si wi fun Sadoku pe, Si tun gbe apoti-ẹri Ọlọrun na pada si ilu: bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ Oluwa, yio si tun mu mi pada wá, yio si fi apoti-ẹri na hàn mi ati ibugbe rẹ̀. Ṣugbọn bi on ba si wi pe, Emi kò ni inu didùn si ọ; wõ, emi niyi, jẹ ki on ki o ṣe si mi gẹgẹ bi o ti tọ́ li oju rẹ̀. Ọba si wi fun Sadoku alufa pe, Iwọ kọ́ ariran? pada si ilu li alafia, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ, Ahimaasi ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari. Wõ, emi o duro ni pẹtẹlẹ iju nì, titi ọ̀rọ o fi ti ọdọ rẹ wá lati sọ fun mi. Sadoku ati Abiatari si gbe apoti-ẹri Ọlọrun pada si Jerusalemu: nwọn si gbe ibẹ̀. Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rẹ̀, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rẹ̀, olukuluku ọkunrin si bò ori rẹ̀, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ. Ẹnikan si sọ fun Dafidi pe, Ahitofeli wà ninu awọn ọlọ̀tẹ̀ Absalomu. Dafidi si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, sọ ìmọ Ahitofeli di asan. O si ṣe, Dafidi de ori oke, nibiti o gbe wolẹ̀ sin Ọlọrun, si wõ, Huṣai ara Arki nì si wá lati pade rẹ̀ ti on ti aṣọ rẹ̀ yiya, ati erupẹ, li ori rẹ̀. Dafidi si wi fun u pe, bi iwọ ba bá mi kọja, iwọ o si jẹ idiwọ fun mi. Bi iwọ ba si pada si ilu, ti o si wi fun Absalomu pe, Emi o ṣe iranṣẹ rẹ, ọba, gẹgẹ bi emi ti ṣe iranṣẹ baba rẹ nigba atijọ, bẹ̃li emi o si jẹ iranṣẹ rẹ nisisiyi: ki iwọ ki o si bà ìmọ Ahitofeli jẹ. Ṣe Sadoku ati Abiatari awọn alufa wà nibẹ pẹlu rẹ? yio si ṣe, ohunkohun ti iwọ ba gbọ́ lati ile ọba wá, iwọ o si sọ fun Sadoku ati Abiatari awọn alufa. Wõ, nwọn si ni ọmọ wọn mejeji nibẹ pẹlu wọn, Ahimaasi ọmọ Sadoku, ati Jonatani ọmọ Abiatari; lati ọwọ́ wọn li ẹnyin o si rán ohunkohun ti ẹnyin ba gbọ́ si mi. Huṣai ọrẹ Dafidi si wá si ilu, Absalomu si wá si Jerusalemu.

II. Sam 15:23-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbogbo ìlú náà sì fi ohùn rara sọkún, gbogbo ènìyàn sì rékọjá; ọba sì rékọjá Àfonífojì Kidironi, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì rékọjá, sí ìhà ọ̀nà ijù. Sì wò ó, Sadoku pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run: wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Abiatari sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá. Ọba sì wí fún Sadoku pé, “Sì tún gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú: bí èmi bá rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ OLúWA, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí òun bá sì wí pé, ‘Èmi kò ní inú dídùn sí ọ,’ wò ó, èmi nìyìí, jẹ́ kí òun ó ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ̀.” Ọba sì wí fún Sadoku àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Ahimasi ọmọ rẹ, àti Jonatani ọmọ Abiatari. Wò ó, èmi ó dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà, títí ọ̀rọ̀ ó fi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá láti sọ fún mi.” Sadoku àti Abiatari sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jerusalẹmu: wọ́n sì gbé ibẹ̀. Dafidi sì ń gòkè lọ ní òkè igi olifi, o sì ń sọkún bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹsẹ̀: gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ. Ẹnìkan sì sọ fún Dafidi pé, “Ahitofeli wà nínú àwọn aṣọ̀tẹ̀ pẹ̀lú Absalomu.” Dafidi sì wí pé, “OLúWA, èmi bẹ̀ ọ́, sọ ìmọ̀ Ahitofeli di asán.” Ó sì ṣe, Dafidi dé orí òkè, níbi tí ó gbé wólẹ̀ sin Ọlọ́run, sì wò ó, Huṣai ará Arki sì wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ yíya, àti erùpẹ̀, lórí rẹ̀. Dafidi sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá bá mi kọjá, ìwọ ó sì jẹ́ ìdíwọ́ fún mi. Bí ìwọ bá sì padà sí ìlú, tí o sì wí fún Absalomu pé, ‘Èmi ó ṣe ìránṣẹ́ rẹ ọba, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ṣe ìránṣẹ́ baba rẹ nígbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nísinsin yìí,’ kí ìwọ sì bá ìmọ̀ Ahitofeli jẹ́. Ṣé Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀? Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ìwọ bá gbọ́ láti ilé ọba wá, ìwọ ó sì sọ fún Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà. Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Ahimasi ọmọ Sadoku, àti Jonatani ọmọ Abiatari; láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yin ó sì rán ohunkóhun tí ẹ̀yin bá gbọ́ sí mi.” Huṣai ọ̀rẹ́ Dafidi sì wá sí ìlú, Absalomu sì wá sí Jerusalẹmu.

II. Sam 15:23-37 Yoruba Bible (YCE)

Gbogbo ìlú bú sẹ́kún bí àwọn eniyan náà ti ń lọ. Ọba rékọjá odò Kidironi, àwọn eniyan rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Gbogbo wọ́n jọ ń lọ sí ọ̀nà apá ijù. Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn. Ọba wí fún Sadoku pé, “Gbé Àpótí Ẹ̀rí náà pada sí ìlú. Bí inú OLUWA bá dùn sí mi, bí mo bá bá ojurere OLUWA pàdé, yóo mú mi pada, n óo tún fi ojú kan Àpótí Ẹ̀rí náà ati ilé OLUWA. Ṣugbọn bí inú rẹ̀ kò bá dùn sí mi, kí ó ṣe mí bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ̀.” Ó tún fi kún un fún Sadoku pé, “Wò ó! Ìwọ ati Abiatari, ẹ pada sí ìlú ní alaafia, mú Ahimaasi, ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari lọ́wọ́. N óo dúró ní ibi tí wọ́n ń gbà la odò kọjá ní ijù níhìn-ín, títí tí n óo fi rí oníṣẹ́ rẹ.” Sadoku ati Abiatari bá gbé àpótí ẹ̀rí pada sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀. Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, Ahitofeli ti darapọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì, Dafidi gbadura sí OLUWA, ó ní, “Jọ̀wọ́, OLUWA, yí gbogbo ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá fún Absalomu pada sí asán.” Nígbà tí Dafidi gun òkè náà dé orí, níbi tí wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run, Huṣai, ará Ariki, wá pàdé rẹ̀ pẹlu aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya, ó sì ti ku eruku sí orí rẹ̀. Dafidi wí fún un pé, “Bí o bá bá mi lọ, ìdíwọ́ ni o óo jẹ́ fún mi. Bí o bá pada sí ìlú, tí o sì sọ fún Absalomu, ọba, pé o ti ṣetán láti sìn ín pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti sin èmi baba rẹ̀, nígbà náà ni o óo ní anfaani láti bá mi yí ìmọ̀ràn Ahitofeli po. Ṣebí Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji wà níbẹ̀, gbogbo ohun tí o bá ti gbọ́ ninu ààfin ọba ni kí o máa sọ fún wọn. Àwọn ọmọ wọn mejeeji, Ahimaasi ati Jonatani wà lọ́dọ̀ wọn. Gbogbo ohun tí ẹ bá gbọ́, kí ẹ máa rán wọn sí mi.” Huṣai bá pada, ó dé Jerusalẹmu bí Absalomu tí ń wọ ìlú bọ̀ gẹ́lẹ́.