SAMUẸLI KEJI 15
15
Absalomu Dìtẹ̀ mọ́ Dafidi
1Lẹ́yìn èyí, Absalomu wá kẹ̀kẹ́ ogun kan, ati àwọn ẹṣin, ati aadọta ọkunrin tí wọn yóo máa sáré níwájú rẹ̀. 2A máa jí ní òwúrọ̀ kutukutu, a sì dúró ní ẹ̀bá ọ̀nà, ní ẹnu ibodè ìlú. Nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ń mú ẹjọ́ bọ̀ wá sọ́dọ̀ ọba, Absalomu á pe olúwarẹ̀ sọ́dọ̀, á bi í pé, “Níbo ni o ti wá?” Lẹ́yìn ìgbà tí ẹni náà bá sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá fún Absalomu tán, 3Absalomu á wí fún un pé, “Wò ó, ẹjọ́ rẹ tọ́, o sì jàre, ṣugbọn ọba kò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀, láti máa gbọ́ irú ẹjọ́ báyìí.” 4Absalomu á tún wá fi kún un pé, “A! Bí wọ́n bá fi mí ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni, bí ẹnikẹ́ni bá ní èdè-àìyedè kan pẹlu ẹlòmíràn, tabi tí ẹnìkan bá fẹ́ gba ohun tíí ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, wọn ìbá máa tọ̀ mí wá, ǹ bá sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún wọn.” 5Bí ẹnikẹ́ni bá súnmọ́ Absalomu láti wólẹ̀, kí ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, Absalomu á tètè na ọwọ́ sí i, á gbá a mú, a sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 6Bẹ́ẹ̀ ni Absalomu máa ń ṣe sí gbogbo àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n bá kó ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba. Nítorí bí ó ti ń ṣe yìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n fẹ́ràn rẹ̀.
7Ní ìparí ọdún kẹrin, Absalomu tọ Dafidi lọ, ó ní, “Kabiyesi, fún mi láàyè kí n lọ sí Heburoni. Mo fẹ́ lọ san ẹ̀jẹ́ kan tí mo jẹ́ fún OLUWA. 8Nígbà tí mo fi wà ní Geṣuri, ní ilẹ̀ Siria, mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, pé bí ó bá mú mi pada sí Jerusalẹmu, n óo lọ sìn ín ní Heburoni.”
9Ọba bá dá a lóhùn pé kí ó máa lọ ní alaafia, Absalomu bá dìde ó lọ sí Heburoni. 10Ṣugbọn Absalomu rán iṣẹ́ àṣírí sí gbogbo ẹ̀yà Israẹli, ó ní, “Tí ẹ bá gbọ́ tí wọ́n fọn fèrè, kí ẹ sọ pé, ‘Absalomu ti di ọba ní Heburoni.’ ” 11Igba ọkunrin ni Absalomu pè, tí wọ́n sì bá a lọ láti Jerusalẹmu. Wọn kò ní èrò ibi lọ́kàn, ní tiwọn, wọn kò sì mọ ohun tí ó wà lọ́kàn Absalomu. 12Nígbà tí Absalomu ń rúbọ lọ́wọ́, ó ranṣẹ sí ìlú Gilo láti lọ pe Ahitofeli ará Gilo, ọ̀kan ninu àwọn olùdámọ̀ràn Dafidi ọba. Ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì ń gbilẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ń pọ̀ sí i.
Dafidi Sá Kúrò ní Jerusalẹmu
13Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.”
14Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.”
15Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dáhùn pé, “Kabiyesi, ohunkohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” 16Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin.
17Bí ọba ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní ìlú, wọ́n dúró níbi ilé tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìlú. 18Gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì ń tò kọjá níwájú rẹ̀; àwọn ẹgbẹta (600) ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Gati náà tò kọjá níwájú rẹ̀. 19Ọba bá kọjú sí Itai ará Gati, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá wa lọ? Pada, kí o lọ dúró ti ọba, àlejò ni ọ́, sísá ni o sá kúrò ní ìlú rẹ wá síhìn-ín. 20Kò sì tíì pẹ́ pupọ tí o dé, kí ló dé tí o fi fẹ́ máa bá mi káàkiri ninu ìrìnkèrindò mi? Èmi gan-an nìyí, n kò tíì mọ ibi tí mò ń lọ. Pada kí àwọn ará ìlú rẹ gbogbo sì máa bá ọ lọ. OLUWA yóo fẹ́ràn ìwọ náà, yóo sì dúró tì ọ́.”
21Ṣugbọn Itai dáhùn pé, “Kabiyesi, mo fi OLUWA búra, bí ẹ̀mí oluwa mi ọba tí ń bẹ láàyè, pé, ibikíbi tí o bá ń lọ ni n óo máa bá ọ lọ, kì báà tilẹ̀ já sí ikú.”
22Dafidi dáhùn, ó ní, “Kò burú.” Itai ati àwọn eniyan rẹ̀, ati àwọn ọmọ kéékèèké, tò kọjá níwájú ọba. 23Gbogbo ìlú bú sẹ́kún bí àwọn eniyan náà ti ń lọ. Ọba rékọjá odò Kidironi, àwọn eniyan rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Gbogbo wọ́n jọ ń lọ sí ọ̀nà apá ijù.
24Sadoku, alufaa, wà láàrin wọn, àwọn ọmọ Lefi sì wà pẹlu rẹ̀, wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí lọ́wọ́. Wọ́n gbé e kalẹ̀ títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi jáde kúrò ní ìlú. Abiatari, alufaa náà wà láàrin wọn. 25Ọba wí fún Sadoku pé, “Gbé Àpótí Ẹ̀rí náà pada sí ìlú. Bí inú OLUWA bá dùn sí mi, bí mo bá bá ojurere OLUWA pàdé, yóo mú mi pada, n óo tún fi ojú kan Àpótí Ẹ̀rí náà ati ilé OLUWA. 26Ṣugbọn bí inú rẹ̀ kò bá dùn sí mi, kí ó ṣe mí bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ̀.” 27Ó tún fi kún un fún Sadoku pé, “Wò ó! Ìwọ ati Abiatari, ẹ pada sí ìlú ní alaafia, mú Ahimaasi, ọmọ rẹ, ati Jonatani ọmọ Abiatari lọ́wọ́. 28N óo dúró ní ibi tí wọ́n ń gbà la odò kọjá ní ijù níhìn-ín, títí tí n óo fi rí oníṣẹ́ rẹ.” 29Sadoku ati Abiatari bá gbé àpótí ẹ̀rí pada sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wà níbẹ̀.
30Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ. 31Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, Ahitofeli ti darapọ̀ mọ́ ọ̀tẹ̀ tí Absalomu ń dì, Dafidi gbadura sí OLUWA, ó ní, “Jọ̀wọ́, OLUWA, yí gbogbo ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá fún Absalomu pada sí asán.”
32Nígbà tí Dafidi gun òkè náà dé orí, níbi tí wọ́n ti máa ń rúbọ sí Ọlọ́run, Huṣai, ará Ariki, wá pàdé rẹ̀ pẹlu aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya, ó sì ti ku eruku sí orí rẹ̀. 33Dafidi wí fún un pé, “Bí o bá bá mi lọ, ìdíwọ́ ni o óo jẹ́ fún mi. 34Bí o bá pada sí ìlú, tí o sì sọ fún Absalomu, ọba, pé o ti ṣetán láti sìn ín pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí o ti sin èmi baba rẹ̀, nígbà náà ni o óo ní anfaani láti bá mi yí ìmọ̀ràn Ahitofeli po. 35Ṣebí Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa mejeeji wà níbẹ̀, gbogbo ohun tí o bá ti gbọ́ ninu ààfin ọba ni kí o máa sọ fún wọn. 36Àwọn ọmọ wọn mejeeji, Ahimaasi ati Jonatani wà lọ́dọ̀ wọn. Gbogbo ohun tí ẹ bá gbọ́, kí ẹ máa rán wọn sí mi.”
37Huṣai bá pada, ó dé Jerusalẹmu bí Absalomu tí ń wọ ìlú bọ̀ gẹ́lẹ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 15: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010