II. A. Ọba 9:14-37

II. A. Ọba 9:14-37 YBCV

Bẹ̃ni Jehu ọmọ Jehoṣafati ọmọ Nimṣi ṣotẹ si Joramu. (Njẹ Joramu ti nṣọ Ramoti-Gileadi, on, ati gbogbo Israeli, nitoriti Hasaeli ọba Siria: Ṣugbọn Joramu ọba ti pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ṣa a, nigbati o ba Hasaeli ọba Siria jà.) Jehu si wipe, Bi o ba ṣe ifẹ inu nyin ni, ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ki o jade lọ, tabi ki o yọ́ lọ kuro ni ilu lati lọ isọ ni Jesreeli. Bẹ̃ni Jehu gùn kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli; nitori Joramu dùbulẹ nibẹ. Ahasiah ọba Juda si sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu. Olùṣọ kan si duro ni ile iṣọ ni Jesreeli, o si ri ẹgbẹ́ Jehu bi o ti mbọ̀ wá, o si wipe, Mo ri ẹgbẹ́ kan. Joramu si wipe, Mu ẹlẹṣin kan, ki o si ranṣẹ lọ ipade wọn, ki o si wipe, Alafia kọ́? Ẹnikan si lọ lori ẹṣin lati pade rẹ̀, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ pe, Iranṣẹ na de ọdọ wọn, ṣugbọn kò si tun pada wá mọ. O si rán ekeji jade lori ẹṣin on si tọ̀ wọn wá, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si dahùn wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan. Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli. O si ṣe, nigbati Joramu ri Jehu li o wipe, Jehu, Alafia kọ́? On si wipe, Alafia kini, niwọ̀nbi iwà-agbère Jesebeli ìya rẹ ati iṣe ajẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tobẹ̃? Joramu si yi ọwọ rẹ̀ pada, o si sá, o si wi fun Ahasiah pe, Ọtẹ̀ de, Ahasiah. Jehu si fi gbogbo agbara rẹ̀ fà ọrun o si ta Joramu lãrin apa rẹ̀ mejeji, ọfà na si gbà ọkàn rẹ̀ jade, o si dojubolẹ ninu kẹkẹ́ rẹ̀. Nigbana ni Jehu sọ fun Bidkari balogun rẹ̀, pe, Gbe e ki o si sọ ọ si oko Naboti ara Jesreeli: sa ranti bi igbati temi tirẹ jumọ ngùn kẹkẹ́ lẹhin Ahabu baba rẹ̀, Oluwa ti sọ ọ̀rọ-ìmọ yi sori rẹ̀. Nitõtọ li ana emi ti ri ẹ̀jẹ Naboti ati ẹ̀jẹ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, li Oluwa wi; emi o si san a fun ọ ni oko yi, li Oluwa wi. Njẹ nitorina, ẹ mu u, ki ẹ si sọ ọ sinu oko na gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Li ọdun ikọkanla Joramu ọmọ Ahabu ni Ahasiah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda. Nigbati Jehu si de Jesreeli, Jesebeli gbọ́; on si le tìrõ, o si ta ori rẹ̀, o si yọju wode ni fèrese. Bi Jehu si ti ngbà ẹnu-ọ̀na wọle, o wipe, Simri ti o pa oluwa rẹ̀ ri alafia bi? On si gbé oju rẹ̀ si òke fèrese, o si wipe, Tani nṣe ti emi? tani? Awọn iwẹ̀fa meji bi mẹta si yọju si i lode. On si wipe, Ẹ tari rẹ̀ silẹ. Nwọn si tari rẹ̀ silẹ: diẹ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ si ta si ara ogiri, ati si ara awọn ẹṣin: on si tẹ̀ ẹ mọlẹ. Nigbati o si wọle, o jẹ, o si mu, o si wipe, Ẹ lọ iwò obinrin egun yi wàyi, ki ẹ si sìn i: nitori ọmọbinrin ọba li on iṣe. Nwọn si lọ isin i; ṣugbọn nwọn kó ri ninu rẹ̀ jù agbari, ati ẹsẹ̀ ati atẹ́lẹwọ rẹ̀ lọ. Nitorina nwọn si tun pada wá, nwọn si sọ fun u. On si wipe, Eyi li ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀ ara Tiṣbi wipe, Ni oko Jesreeli li awọn aja yio jẹ ẹran-ara Jesebeli: Okú Jesebeli yio si dàbi imí ni igbẹ́, ni oko Jesreeli; tobẹ̃ ti nwọn kì yio wipe, Jesebeli li eyi.