II. A. Ọba 9:14-37

II. A. Ọba 9:14-37 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bẹ̃ni Jehu ọmọ Jehoṣafati ọmọ Nimṣi ṣotẹ si Joramu. (Njẹ Joramu ti nṣọ Ramoti-Gileadi, on, ati gbogbo Israeli, nitoriti Hasaeli ọba Siria: Ṣugbọn Joramu ọba ti pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ṣa a, nigbati o ba Hasaeli ọba Siria jà.) Jehu si wipe, Bi o ba ṣe ifẹ inu nyin ni, ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ki o jade lọ, tabi ki o yọ́ lọ kuro ni ilu lati lọ isọ ni Jesreeli. Bẹ̃ni Jehu gùn kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli; nitori Joramu dùbulẹ nibẹ. Ahasiah ọba Juda si sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu. Olùṣọ kan si duro ni ile iṣọ ni Jesreeli, o si ri ẹgbẹ́ Jehu bi o ti mbọ̀ wá, o si wipe, Mo ri ẹgbẹ́ kan. Joramu si wipe, Mu ẹlẹṣin kan, ki o si ranṣẹ lọ ipade wọn, ki o si wipe, Alafia kọ́? Ẹnikan si lọ lori ẹṣin lati pade rẹ̀, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ pe, Iranṣẹ na de ọdọ wọn, ṣugbọn kò si tun pada wá mọ. O si rán ekeji jade lori ẹṣin on si tọ̀ wọn wá, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si dahùn wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan. Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli. O si ṣe, nigbati Joramu ri Jehu li o wipe, Jehu, Alafia kọ́? On si wipe, Alafia kini, niwọ̀nbi iwà-agbère Jesebeli ìya rẹ ati iṣe ajẹ́ rẹ̀ ti pọ̀ tobẹ̃? Joramu si yi ọwọ rẹ̀ pada, o si sá, o si wi fun Ahasiah pe, Ọtẹ̀ de, Ahasiah. Jehu si fi gbogbo agbara rẹ̀ fà ọrun o si ta Joramu lãrin apa rẹ̀ mejeji, ọfà na si gbà ọkàn rẹ̀ jade, o si dojubolẹ ninu kẹkẹ́ rẹ̀. Nigbana ni Jehu sọ fun Bidkari balogun rẹ̀, pe, Gbe e ki o si sọ ọ si oko Naboti ara Jesreeli: sa ranti bi igbati temi tirẹ jumọ ngùn kẹkẹ́ lẹhin Ahabu baba rẹ̀, Oluwa ti sọ ọ̀rọ-ìmọ yi sori rẹ̀. Nitõtọ li ana emi ti ri ẹ̀jẹ Naboti ati ẹ̀jẹ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, li Oluwa wi; emi o si san a fun ọ ni oko yi, li Oluwa wi. Njẹ nitorina, ẹ mu u, ki ẹ si sọ ọ sinu oko na gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ṣugbọn nigbati Ahasiah ọba Juda ri eyi, o gbà ọ̀na ile ọgba salọ. Jehu si lepa rẹ̀ o si wipe, Ẹ ta a ninu kẹkẹ́ pẹlu. Nwọn si ṣe bẹ̃ li atigòke si Guri, ti o wà leti Ibleamu. O si salọ si Megiddo, o si kú nibẹ. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e ninu kẹkẹ́ lọ si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni bojì rẹ̀ pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Li ọdun ikọkanla Joramu ọmọ Ahabu ni Ahasiah bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda. Nigbati Jehu si de Jesreeli, Jesebeli gbọ́; on si le tìrõ, o si ta ori rẹ̀, o si yọju wode ni fèrese. Bi Jehu si ti ngbà ẹnu-ọ̀na wọle, o wipe, Simri ti o pa oluwa rẹ̀ ri alafia bi? On si gbé oju rẹ̀ si òke fèrese, o si wipe, Tani nṣe ti emi? tani? Awọn iwẹ̀fa meji bi mẹta si yọju si i lode. On si wipe, Ẹ tari rẹ̀ silẹ. Nwọn si tari rẹ̀ silẹ: diẹ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ si ta si ara ogiri, ati si ara awọn ẹṣin: on si tẹ̀ ẹ mọlẹ. Nigbati o si wọle, o jẹ, o si mu, o si wipe, Ẹ lọ iwò obinrin egun yi wàyi, ki ẹ si sìn i: nitori ọmọbinrin ọba li on iṣe. Nwọn si lọ isin i; ṣugbọn nwọn kó ri ninu rẹ̀ jù agbari, ati ẹsẹ̀ ati atẹ́lẹwọ rẹ̀ lọ. Nitorina nwọn si tun pada wá, nwọn si sọ fun u. On si wipe, Eyi li ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀ ara Tiṣbi wipe, Ni oko Jesreeli li awọn aja yio jẹ ẹran-ara Jesebeli: Okú Jesebeli yio si dàbi imí ni igbẹ́, ni oko Jesreeli; tobẹ̃ ti nwọn kì yio wipe, Jesebeli li eyi.

II. A. Ọba 9:14-37 Yoruba Bible (YCE)

Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ mọ́ Joramu. (Ní àkókò yìí Joramu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli ń ṣọ́ Hasaeli ọba Siria ní Ramoti Gileadi; ṣugbọn Joramu ọba ti lọ sí Jesireeli láti tọ́jú ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun Siria.) Jehu sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Bí ẹ bá wà lẹ́yìn mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò ní ìlú láti lọ ròyìn fún wọn ní Jesireeli.” Jehu gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó lọ sí Jesireeli nítorí ibẹ̀ ni Joramu ọba wà, Ahasaya, ọba Juda sì wá bẹ̀ ẹ́ wò níbẹ̀. Ọ̀kan ninu àwọn aṣọ́nà tí ó wà ninu ilé ìṣọ́ ní Jesireeli rí i tí Jehu ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ń bọ̀. Ó sì kígbe pé, “Mo rí àwọn ọkunrin kan tí wọ́n ń gun kẹ̀kẹ́ ogun bọ̀.” Joramu dáhùn pé, “Rán ẹlẹ́ṣin kan láti bèèrè bóyá alaafia ni.” Ẹlẹ́ṣin kan lọ pàdé rẹ̀, ó ní, “Ọba wí pé, ṣé alaafia ni?” Jehu dá a lóhùn pé, “Kí ni o ní ṣe pẹlu alaafia? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ náà wí pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn ṣugbọn kò pada wá.” Wọ́n bá tún rán oníṣẹ́ mìíràn lọ láti bèèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ Jehu. Ó tún dáhùn pé “Kí ni o fẹ́ fi alaafia ṣe? Bọ́ sẹ́yìn mi.” Olùṣọ́ bá tún jíṣẹ́ fun ọba pé, “Oníṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣugbọn kò pada.” Ó tún fi kún un pé, “Wọ́n ń wa kẹ̀kẹ́ ogun wọn bíi Jehu, ọmọ Nimṣi, nítorí wọ́n ń wà á pẹlu ibinu.” Joramu ọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé kẹ̀kẹ́ ogun òun wá, wọ́n sì gbé e wá fún un. Joramu ọba ati Ahasaya, ọba Juda sì jáde lọ pàdé Jehu, olukuluku ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Wọ́n pàdé rẹ̀ ninu oko Naboti ara Jesireeli. Joramu bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni?” Jehu dáhùn pé, “Alaafia ṣe lè wà níwọ̀n ìgbà tí ìwà àgbèrè ati àjẹ́ ìyá rẹ ṣì wà sibẹ.” Joramu bá kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí, Ahasaya!” Ó yí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pada, ó ń sá lọ. Jehu fi gbogbo agbára ta ọfà rẹ̀, ó bá Joramu lẹ́yìn, ó wọ inú ọkàn rẹ̀ lọ, Joramu sì kú sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Jehu sọ fún Bidikari, ẹni tí ń ru ihamọra rẹ̀, ó ní, “Gbé òkú rẹ̀ kí o jù ú sinu oko Naboti. Ṣé o ranti pé, nígbà tí èmi pẹlu rẹ ń gun kẹ̀kẹ́ ogun lẹ́yìn Ahabu baba rẹ̀, OLUWA sọ ọ̀rọ̀ wọnyi nípa Ahabu, pé, ‘Mo rí i bí o ti pa Naboti ati àwọn ọmọ rẹ̀ lánàá, dájúdájú n óo jẹ ọ́ níyà ninu oko kan náà.’ Nítorí náà gbé òkú rẹ̀ jù sinu oko Naboti gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA.” Nígbà tí Ahasaya rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá gba ọ̀nà Beti Hagani lọ. Jehu bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọkunrin rẹ̀ pé kí wọ́n ta á lọ́fà! Wọ́n sì ta á lọ́fà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ní ọ̀nà Guri lẹ́bàá Ibileamu, ó sá lọ sí Megido, níbẹ̀ ni ó sì kú sí. Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan lọ sí Jerusalẹmu. Wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ahasaya jọba ní ilẹ̀ Juda ní ọdún kọkanla tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli. Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè. Bí Jehu ti gba ẹnu ọ̀nà wọlé, Jesebẹli kígbe pé, “Ṣé alaafia ni, Simiri? Ìwọ tí o pa oluwa rẹ!” Jehu bá gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ní, “Ta ló wà lẹ́yìn mi ninu yín?” Àwọn ìwẹ̀fà meji tabi mẹta sì yọjú sí i láti ojú fèrèsé. Jehu bá ké sí wọn, ó ni, “Ẹ Jù ú sílẹ̀.” Wọ́n bá ju Jesebẹli sí ìsàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sí ara ògiri ati sí ara àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jehu sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kọjá. Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó mu, lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹ lọ sin òkú obinrin ẹni ègún yìí nítorí pé ọmọ ọba ni.” Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ sin òkú náà kò rí nǹkankan àfi agbárí, ati egungun ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n pada wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jehu, ó ní, “OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Elija, iranṣẹ rẹ̀ pé, ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli. Òkú rẹ̀ yóo fọ́n ká bí ìgbẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè dá a mọ̀ mọ́.”

II. A. Ọba 9:14-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi, dìtẹ̀ sí Joramu. (Nísinsin yìí Joramu àti gbogbo Israẹli ti ń dáàbò bo Ramoti Gileadi nítorí Hasaeli ọba Aramu: Ṣùgbọ́n ọba Joramu ti padà sí Jesreeli láti lọ sàn nínú ọgbẹ́ tí àwọn ará Aramu ti dá sí i lára nínú ogun pẹ̀lú ọba Hasaeli ti Aramu). Jehu wí pé, “Tí èyí bá jẹ́ ọ̀nà tí ò ń rò, má ṣe jẹ́ kí ẹnìkankan kí ó yọ jáde nínú ìlú ńlá láti lọ sọ ìròyìn náà ní Jesreeli.” Nígbà náà Jehu wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jesreeli, nítorí Joramu ń sinmi níbẹ̀ àti Ahasiah ọba Juda sì sọ̀kalẹ̀ láti wá wò Joramu. Nígbà tí olùṣọ́ kan tí ó dúró ní ilé ìṣọ́ ní Jesreeli, rí ọ̀wọ́ ogun Jehu tí wọ́n ń súnmọ́ tòsí, ó pè jáde, “Mo rí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó ń bọ̀.” “Mú ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kan,” Joramu pa á láṣẹ. “Rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wọn kí o sì béèrè pé, ‘Ṣé ẹ̀yin wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” Ọkùnrin ẹlẹ́ṣin náà, lọ láti lọ bá Jehu ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba wí: ‘Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?’ ” “Kí ni ìwọ ní ṣe pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu sì dáhùn. “Bọ́ sí ẹ̀yìn mi.” Olùṣọ́ náà sì wí fún un pé, “ìránṣẹ́ náà ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, ọba rán ọkùnrin ẹlẹ́ṣin kejì, Nígbà náà ó wá sí ọ̀dọ̀ wọn, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba sọ: “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà?” Jehu dáhùn, “Dúró sí ẹ̀yìn mi.” Olùṣọ́ náà sì fi sùn. “Ó ti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kò tún padà wá mọ́ pẹ̀lú. Wíwá rẹ̀ sì dàbí ti Jehu ọmọ Nimṣi, ó ń wa kẹ̀kẹ́ bí ti aṣiwèrè.” “Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Nígbà tí Joramu rí Jehu, ó béèrè pé, “Ṣé ìwọ wá pẹ̀lú àlàáfíà, Jehu?” “Báwo ni àlàáfíà yóò ṣe wà,” Jehu dáhùn, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìbọ̀rìṣà àti iṣẹ́ àjẹ́ ti màmá rẹ Jesebeli di púpọ̀?” Joramu yí ọwọ́ rẹ̀ padà, ó sì sálọ, ó sì ń pe Ahasiah, “ọ̀tẹ̀ dé, Ahasiah!” Nígbà náà, Jehu fa ọrun rẹ̀, ó sì yin Joramu láàrín èjìká méjèèjì. Ọfà náà sì wọ inú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀ láti orí kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí OLúWA sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀: ‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni OLúWA wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ OLúWA.” Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. (Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.) Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé. Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?” Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn. Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin ín, wọn kò rí nǹkan kan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. Wọ́n padà lọ sọ fún Jehu, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah ará Tiṣibi wí pé: Ní orí oko Jesreeli ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran-ara Jesebeli. Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, ‘Jesebeli ni èyí.’ ”