II. A. Ọba 25

25
Ìṣubú Jerusalẹmu
(II. Kro 36:13-21; Jer 52:3b-11)
1O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣù kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣù, ni Nebukadnessari ọba Babeli de, on, ati gbogbo ogun rẹ̀, si Jerusalemu, o si dotì i; nwọn si mọdi tì i yika kiri.
2A si dotì ilu na titi di ọdun ikọkanla Sedekiah.
3Ati li ọjọ kẹsan oṣù kẹrin, iyàn mu gidigidi ni ilu, kò si si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.
4Ilu na si fọ́, gbogbo awọn ọkunrin ologun si gbà ọ̀na bodè lãrin odi meji, ti o wà leti ọgbà ọba, salọ li oru; (awọn ara Kaldea si yi ilu na kakiri;) ọba si ba ọ̀na pẹ̀tẹlẹ lọ.
5Ogun awọn ara Kaldea si lepa ọba, nwọn si ba a ni pẹ̀tẹlẹ Jeriko: gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.
6Bẹ̃ni nwọn mu ọba, nwọn si mu u gòke lọ si ọdọ ọba Babeli ni Ribla; nwọn si sọ ọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
7Nwọn si pa awọn ọmọ Sedekiah li oju rẹ̀, nwọn si fọ Sedekiah li oju, nwọn si fi ẹwọn idẹ dè e, nwọn si mu u lọ si Babeli.
Pípa Tẹmpili Run
(Jer 52:12-23)
8Ati li oṣù karun, li ọjọ keje oṣù, ti iṣe ọdun ikọkandilogun Nebukadnessari ọba, ọba Babeli, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ, iranṣẹ ọba Babeli, wá si Jerusalemu:
9O si fi ile Oluwa joná, ati ile ọba, ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile enia nla li o fi iná sun.
10Gbogbo ogun awọn ara Kaldea ti o wà lọdọ olori ẹ̀ṣọ, si wó odi Jerusalemu palẹ yika kiri.
11Ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu ati awọn isansa ti o ya tọ̀ ọba, Babeli lọ, pẹlu ọ̀pọlọpọ enia ti o kù, ni Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ kó lọ.
12Ṣugbọn olori ẹ̀ṣọ fi awọn talakà ilẹ na silẹ, lati mã ṣe alabojuto àjara ati lati mã ṣe aroko.
13Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ ni ile Oluwa, ati ijoko wọnni, ati agbada-nla idẹ ti o wà ni ile Oluwa, li awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó idẹ wọn lọ si Babeli.
14Ati ikòko wọnni, ati ọkọ wọnni, ati alumagàji fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun-èlo wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ, ni nwọn kó lọ.
15Ati ohun ifọnná wọnni, ati ọpọ́n wọnni, eyi ti iṣe ti wura, ni wura, ati eyi ti iṣe ti fadakà ni fadakà, ni olori ẹ̀ṣọ kó lọ.
16Awọn ọ̀wọn meji, agbada-nla kan, ati ijoko wọnni ti Solomoni ti ṣe fun ile Oluwa; idẹ ni gbogbo ohun-èlo wọnyi, alaini ìwọn ni.
17Giga ọwọ̀n kan ni igbọ̀nwọ mejidilogun, ati ọnà-ori rẹ̀ idẹ ni: ati giga ọnà-ori na ni igbọ̀nwọ mẹta; ati iṣẹ wiwun na, ati awọn pomegranate ti o wà lori ọnà-ori na yika kiri, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹgẹ bi awọn wọnyi si ni ọwọ̀n keji pẹlu iṣẹ wiwun.
A kó àwọn eniyan Juda lọ sí Babilonii
(Jer 52:24-27)
18Olori ẹ̀ṣọ si mu Seraiah olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah alufa keji, ati awọn olùṣọ iloro mẹta.
19Ati lati inu ilu, o mu iwẹ̀fa kan ti a fi ṣe olori awọn ologun, ati ọkunrin marun ninu awọn ti o wà niwaju ọba, ti a ri ni ilu, ati akọwe olori ogun, ti ntò awọn enia ilẹ na, ati ọgọta ọkunrin ninu awọn enia ilẹ na ti a ri ni ilu.
20Nebusaradani olori ẹ̀ṣọ si kó awọn wọnyi, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.
21Ọba Babeli si kọlù wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.
Gedalaya, Gomina Juda
(Jer 40:7-9; 41:1-3)
22Ati awọn enia ti o kù ni ilẹ Juda, ti Nebukadnessari ọba Babeli fi silẹ, ani, o fi Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, jẹ bãlẹ wọn.
23Nigbati gbogbo awọn olori ogun, awọn ati awọn ọkunrin wọn, si gbọ́ pe ọba Babeli ti fi Gedaliah jẹ bãlẹ, nwọn tọ̀ Gedaliah wá ni Mispa, ani Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ati Johanani ọmọ Karea, ati Seraiah ọmọ Tanhumeti ara Netofati, ati Jaasaniah ọmọ ara Maaka, awọn ati awọn ọkunrin wọn.
24Gedaliah si bura fun wọn, ati fun awọn ọkunrin wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru lati sìn awọn ara Kaldea: ẹ mã gbe ilẹ na, ki ẹ si mã sìn ọba Babeli; yio si dara fun nyin.
25O si ṣe li oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama ninu iru ọmọ ọba, wá ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, o si kọlù Gedaliah, o si kú, ati awọn ara Juda ati awọn ara Kaldea ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Mispa.
26Ati gbogbo enia, ti ewe ti àgba, ati awọn olori ogun, si dide, nwọn si wá si Egipti: nitoriti nwọn bẹ̀ru ara Kaldea.
A dá Jehoiakini Sílẹ̀ kúrò Ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
(Jer 52:31-34)
27O si ṣe li ọdun kẹtadilogoji igbèkun Jehoiakini ọba Juda, li oṣù kejila, li ọjọ kẹtadilọgbọn oṣù, Efil-merodaki ọba Babeli, li ọdun ti o bẹ̀rẹ si ijọba, o gbé ori Jehoiakini ọba Juda soke kuro ninu tubu;
28O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbé ìtẹ rẹ̀ ga jù ìtẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli.
29O si pàrọ awọn aṣọ tubu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.
30Ati ipin onjẹ tirẹ̀, jẹ ipin onjẹ ti ọba nfi fun u nigbagbogbo, iye kan li ojojumọ, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. A. Ọba 25: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀