I. Kro Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìwé Kronika Kin-in-ni ati Ekeji sọ ìtàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Samuẹli Kin-in-ni ati Ekeji, ati ti inú ìwé Àwọn Ọba. Ṣugbọn bí ìwé Kronika ṣe gbé ìtàn tirẹ̀ kalẹ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn yòókù. Ìdí meji pataki ni Ìwé Kronika tọ́ka sí pé ó fa àyípadà ìjọba Israẹli, láti ètò yíyan adájọ́ gẹ́gẹ́ bí olórí, sí ètò yíyan ọba láàrin àwọn eniyan.
(1) Ekinni ni láti fihàn pé pẹlu gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Israẹli ati ti Juda, Ọlọrun ṣì ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lórí orílẹ̀-èdè náà nípasẹ̀ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Juda. Òǹkọ̀wé yìí lo àṣeyọrí tí àwọn ọba kan ṣe láti fi gbe akiyesi rẹ̀ lẹ́sẹ̀: Ó tọ́ka sí àṣeyọrí àwọn ọba olókìkí bíi Dafidi ati Solomoni, àwọn àtúnṣe tí àwọn ọba bíi Jehoṣafati, Hesekaya ati Josaya ṣe, ati àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọrun.
(2) Ìdí keji ni láti ṣe àlàyé bí ìjọ́sìn ninu Tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu ṣe bẹ̀rẹ̀, pàápàá ètò àwọn àlùfáà ati àwọn ọmọ Lefi, ati ìlànà ìjọ́sìn, Dafidi ni wọ́n gbà pé ó ṣe ètò ati ìlànà náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Solomoni ni ó kọ́ Tẹmpili, Dafidi ni ó gba ògo gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó pilẹ̀ rẹ̀ tí ó sì fi ìlànà ìsìn lélẹ̀.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ati ìrandíran wọn 1:1—9:44
Ikú Saulu 10:1-14
Ìjọba Dafidi 11:1—29:30
a. Ọpọlọpọ ìdààmú ati àṣeyọrí rẹ̀ 11:1—22:1
b. Ìpalẹ̀mọ́ fún kíkọ́ Tẹmpili 22:2—29:30

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa