II. A. Ọba 23
23
Josaya pa Ìbọ̀rìṣà Run
(II. Kro 34:3-7,29-33)
1ỌBA si ranṣẹ, nwọn si pè gbogbo awọn àgba Juda ati Jerusalemu jọ sọdọ rẹ̀.
2Ọba si gòke lọ sinu ile Oluwa, ati gbogbo awọn enia Juda ati gbogbo olugbe Jerusalemu pẹlu rẹ̀, ati awọn alufa, ati awọn woli ati gbogbo enia, ati ewe ati àgba: o si kà gbogbo ọ̀rọ inu iwe majẹmu na ti a ri ninu ile Oluwa li eti wọn.
3Ọba si duro ni ibuduro na, o si dá majẹmu niwaju Oluwa, lati mã fi gbogbo aìya ati gbogbo ọkàn rìn tọ̀ Oluwa lẹhin, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati ẹri rẹ̀, ati aṣẹ rẹ̀, lati mu ọ̀rọ majẹmu yi ṣẹ, ti a ti kọ ninu iwe yi. Gbogbo awọn enia si duro si majẹmu na.
4Ọba si paṣẹ fun Hilkiah olori alufa, ati awọn alufa ẹgbẹ keji, ati awọn alabojuto iloro, lati kó gbogbo ohun-èlo ti a ṣe fun Baali, ati fun ere òriṣa, ati fun gbogbo ogun ọrun jade kuro ni tempili Oluwa: o si sun wọn lẹhin ode Jerusalemu ninu pápa Kidroni, o si kó ẽru wọn lọ si Beteli.
5O si dá awọn baba-loriṣa lẹkun, ti awọn ọba Juda ti yàn lati ma sun turari ni ibi giga ni ilu Juda wọnni, ati ni ibi ti o yi Jerusalemu ka; awọn pẹlu ti nsun turari fun Baali, fun õrùn, ati fun òṣupa, ati fun awọn àmi mejila ìrawọ, ati fun gbogbo ogun ọrun.
6O si gbé ere-oriṣa jade kuro ni ile Oluwa, sẹhin ode Jerusalemu lọ si odò Kidroni, o si sun u nibi odò Kidroni, o si lọ̀ ọ lũlu, o si dà ẽrú rẹ̀ sori isà-okú awọn ọmọ enia na.
7O si wó ile awọn ti nhù ìwa panṣaga, ti mbẹ leti ile Oluwa, nibiti awọn obinrin wun aṣọ-agọ fun ere-oriṣa.
8O si kó gbogbo awọn alufa jade kuro ni ilu Juda wọnni, o si sọ ibi giga wọnni di ẽri nibiti awọn alufa ti sun turari, lati Geba titi de Beer-ṣeba, o si wó ibi giga ẹnu-ibodè wọnni ti mbẹ ni atiwọ̀ ẹnu-ibodè Joṣua bãlẹ ilu, ti mbẹ lapa osi ẹni, ni atiwọ̀ ẹnu-ibode ilu.
9Ṣugbọn awọn alufa ibi giga wọnni kò gòke wá si ibi pẹpẹ Oluwa ni Jerusalemu, ṣugbọn nwọn jẹ ninu àkara alaiwu lãrin awọn arakunrin wọn.
10On si sọ Tofeti di ẽri, ti mbẹ ni afonifojì awọn ọmọ Hinnomu, ki ẹnikan ki o máṣe mu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là ãrin iná kọja fun Moleki.
11O si mu ẹṣin wọnni kuro ti awọn ọba Juda ti fi fun õrun, ni atiwọ̀ inu ile Oluwa lẹba iyẹ̀wu Natan-meleki iwẹ̀fa, ti o ti wà ni agbegbe tempili, o si fi iná sun kẹkẹ́ õrun wọnni.
12Ati pẹpẹ wọnni ti mbẹ lori iyara òke Ahasi, ti awọn ọba Juda ti tẹ́, ati pẹpẹ wọnni ti Manasse ti tẹ́ li ãfin mejeji ile Oluwa ni ọba wó lulẹ, o si yara lati ibẹ, o si da ekuru wọn sinu odò Kidroni.
13Ati ibi giga wọnni ti o wà niwaju Jerusalemu, ti o wà li ọwọ ọtún òke idibàjẹ, ti Solomoni ọba Israeli ti kọ́ fun Aṣtoreti ohun irira awọn ara Sidoni, ati fun Kemoṣi ohun irira awọn ara Moabu, ati fun Milkomu ohun-irira awọn ọmọ Ammoni li ọba sọ di ẽri.
14O si fọ́ awọn ere na tũtu, o si wó awọn ere-oriṣa lulẹ, o si fi egungun enia kún ipò wọn.
15Ati pẹlu, pẹpẹ ti o ti wà ni Beteli, ati ibi giga ti Jeroboamu ọmọ Nebati, ẹniti o mu Israeli ṣẹ̀, ti tẹ́, ati pẹpẹ na, ati ibi giga na ni o wó lulẹ, o si sun ibi giga na, o si lọ̀ ọ lũlu, o si sun ere-oriṣa na.
16Bi Josiah si ti yira pada, o ri awọn isà-okú ti o wà lori òke, o si ranṣẹ, o si kó awọn egungun lati inu isà wọnni kuro, o si sun wọn lori pẹpẹ na, o si sọ ọ di ẽri, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti enia Ọlọrun nì ti kede, ẹniti o kede ọ̀ro wọnyi.
17Nigbana li o wipe, Ọwọ̀n isa-okú wo li eyi ti mo ri nì? Awọn enia ilu na si sọ fun u pe, Isà-okú enia Ọlọrun nì ni, ti o ti Juda wá, ti o si kede nkan wọnyi ti iwọ ti ṣe si pẹpẹ Beteli.
18On si wipe, Jọwọ rẹ̀; máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mu egungun rẹ̀ kuro. Bẹ̃ni nwọn jọwọ egungun rẹ̀ lọwọ, pẹlu egungun woli ti o ti Samaria wá.
19Ati pẹlu gbogbo ile ibi-giga wọnni ti o wà ni ilu Samaria wọnni, ti awọn ọba Israeli ti kọ́ lati rú ibinu Oluwa soke ni Josiah mu kuro, o si ṣe si wọn gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti o ṣe ni Beteli.
20O si pa gbogbo awọn alufa ibi-giga wọnni ti o wà nibẹ lori awọn pẹpẹ na, o si sun egungun enia lori wọn, o si pada si Jerusalemu.
Josaya Ọba ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá
(II. Kro 35:1-19)
21Ọba si paṣẹ fun gbogbo enia, wipe, Pa irekọja mọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin, bi a ti kọ ọ ninu iwe majẹmu yi.
22Nitõtọ a kò ṣe iru irekọja bẹ̃ lati ọjọ awọn onidajọ ti ndajọ ni Israeli, tabi ni gbogbo ọjọ awọn ọba Israeli tabi awọn ọba Juda;
23Ṣugbọn li ọdun kejidilogun Josiah ọba, ni a pa irekọja yi mọ́ fun Oluwa ni Jerusalemu.
Àwọn Àtúnṣe Mìíràn tí Josaya Ṣe
24Ati pẹlu awọn ti mba awọn okú lò, ati awọn oṣo, ati awọn ere, ati awọn oriṣa, ati gbogbo irira ti a ri ni ilẹ Juda ati ni Jerusalemu ni Josiah kó kuro, ki o le mu ọ̀rọ ofin na ṣẹ ti a ti kọ sinu iwe ti Hilkiah alufa ri ni ile Oluwa.
25Kò si si ọba kan ṣãju rẹ̀, ti o dabi rẹ̀, ti o yipada si Oluwa tinutinu ati tọkàntọkàn ati pẹlu gbogbo agbara rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo ofin Mose; bẹ̃ni lẹhin rẹ̀, kò si ẹnikan ti o dide ti o dàbi rẹ̀.
26Ṣugbọn Oluwa kò yipada kuro ninu mimuná ibinu nla rẹ̀, eyiti ibinu rẹ̀ fi ràn si Juda, nitori gbogbo imunibinu ti Manasse ti fi mu u binu.
27Oluwa si wipe, Emi o si mu Juda kuro loju mi pẹlu, bi mo ti mu Israeli kuro, emi o si ta ilu Jerusalemu yi nù, ti mo ti yàn, ati ile eyiti mo wipe, Orukọ mi yio wà nibẹ.
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya
(II. Kro 35:20—36:1)
28Ati iyokù iṣe Josiah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
29Li ọjọ rẹ̀ ni Farao-Neko ọba Egipti dide ogun si ọba Assiria li odò Euferate: Josiah ọba si dide si i; on si pa a ni Megiddo, nigbati o ri i.
30Awọn iranṣẹ rẹ̀ si gbé e li okú ninu kẹkẹ́ lati Megiddo lọ, nwọn si mu u wá si Jerusalemu, nwọn si sìn i ni isà-okú on tikalarẹ̀. Awọn enia ilẹ na si mu Jehoahasi ọmọ Josiah, nwọn si fi ororo yàn a, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀.
Jehoahasi, Ọba Juda
(II. Kro 36:2-4)
31Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah ti Libna,
32On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.
33Farao-Neko si fi i sinu idè ni Ribla, ni ilẹ Hamati, ki o má ba jọba ni Jerusalemu; o si fi ilẹ na si abẹ isìn li ọgọrun talenti fadakà, ati talenti wura.
34Farao-Neko si fi Eliakimu ọmọ Josiah jẹ ọba ni ipò Josiah baba rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu, o si mu Jehoahasi kuro; on si wá si Egipti, o si kú nibẹ.
Jehoiakimu Ọba Juda
(II. Kro 36:5-8)
35Jehoiakimu si fi fadakà ati wura na fun Farao; ṣugbọn o bu owo-odè fun ilẹ na lati san owo na gẹgẹ bi ofin Farao: o fi agbara gbà fadakà ati wurà na lọwọ awọn enia ilẹ na, lọwọ olukuluku gẹgẹ bi owo ti a bù fun u, lati fi fun Farao-Neko.
36Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni Jehoiakimu nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Sebuda, ọmọbinrin Bedaiah ti Ruma.
37On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn baba rẹ̀ ti ṣe.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.