II. A. Ọba 22

22
Josaya, Ọba Juda
(II. Kro 34:1-2)
1ẸNI ọdun mẹjọ ni Josiah nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun mọkanlelọgbọ̀n ni Jerusalemu, Orukọ iya rẹ̀ ni Jedida, ọmọbinrin Adaiah ti Boskati.
2On si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa o si rìn li ọ̀na Dafidi baba rẹ̀ gbogbo, kò si yipada si apa ọ̀tún tabi si apa òsi.
Wọ́n rí Ìwé Òfin
(II. Kro 34:8-28)
3O si ṣe li ọdun kejidilogun Josiah ọba li ọba rán Ṣafani ọmọ Asaliah ọmọ Mesullamu, akọwe, si ile Oluwa, wipe,
4Gòke tọ̀ Hilkiah olori alufa lọ, ki o le ṣirò iye fadakà ti a mu wá sinu ile Oluwa, ti awọn olùtọju iloro ti kojọ lọwọ awọn enia:
5Ẹ si jẹ ki wọn ki o fi le awọn olùṣe iṣẹ na lọwọ, ti nṣe alabojuto ile Oluwa: ki ẹ si jẹ ki wọn ki o fi fun awọn olùṣe iṣẹ na ti mbẹ ninu ile Oluwa, lati tun ibi ẹya ile na ṣe.
6Fun awọn gbẹnagbẹna, ati fun awọn akọle, ati awọn ọ̀mọle, lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tún ile na ṣe.
7Ṣugbọn a kò ba wọn ṣe iṣirò owo ti a fi le wọn lọwọ, nitoriti nwọn ṣe otitọ.
8Hilkiah olori alufa si sọ fun Ṣafani akọwe pe, Emi ri iwe ofin ni ile Oluwa. Hilkiah si fi iwe na fun Ṣafani, on si kà a.
9Ṣafani akọwe si wá sọdọ ọba, o si tún mu èsi pada fun ọba wá, o si wipe, Awọn iranṣẹ rẹ ti kó owo na jọ ti a ri ni ile na, nwọn si ti fi le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, ti nṣe alabojuto ile Oluwa.
10Ṣafani akọwe si fi hàn ọba, pe, Hilkiah alufa fi iwe kan le mi lọwọ. Ṣafani si kà a niwaju ọba.
11O si ṣe, nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ inu iwe ofin na, o si fà aṣọ rẹ̀ ya.
12Ọba si paṣẹ fun Hilkiah alufa, ati Ahikamu ọmọ Ṣafani, ati Akbori ọmọ Mikaiah, ati Ṣafani akọwe, ati Asahiah iranṣẹ ọba wipe,
13Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Oluwa fun mi, ati fun awọn enia, ati fun gbogbo Juda, niti ọ̀rọ iwe yi ti a ri: nitori titobi ni ibinu Oluwa ti o rú si wa, nitori awọn baba wa kò fi eti si ọ̀rọ iwe yi, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọwe silẹ fun wa.
14Bẹ̃ni Hilkiah alufa, ati Ahikamu, ati Akbori, ati Ṣafani, ati Asahiah tọ̀ Hulda woli obinrin lọ, aya Ṣallumu, ọmọ Tikfa, ọmọ Harhasi, alabojuto aṣọ (njẹ on ngbe Jerusalemu niha keji); nwọn si ba a sọ̀rọ.
15On si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Sọ fun ọkunrin ti o rán nyin si mi pe,
16Bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, emi o mu ibi bá ibiyi, ati bá awọn ara ilu na, ani gbogbo ọ̀rọ iwe na ti ọba Juda ti kà.
17Nitoriti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si ti nsun turari fun awọn ọlọrun miran, ki nwọn ki o le fi gbogbo iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu; nitorina ibinu mi yio rú si ibi yi, kì yio si rọlẹ.
18Ṣugbọn fun ọba Juda ti o rán nyin wá ibère lọdọ Oluwa, bayi li ẹnyin o sọ fun u, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ọ̀rọ wọnni ti iwọ ti gbọ́:
19Nitoriti ọkàn rẹ rọ̀, ti iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, nigbati iwọ gbọ́ eyiti mo sọ si ibi yi, ati si awọn ara ilu na pe, nwọn o di ahoro ati ẹni-ègun, ti iwọ si fà aṣọ rẹ ya, ti o si sọkun niwaju mi; emi pẹlu ti gbọ́ tirẹ, li Oluwa wi.
20Nitorina kiyesi i, emi o kó ọ jọ sọdọ awọn baba rẹ, a o si kó ọ jọ sinu isà-okú rẹ li alafia; oju rẹ kì o si ri gbogbo ibi ti emi o mu wá bá ibi yi. Nwọn si tún mu èsi fun ọba wá.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. A. Ọba 22: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀