II. A. Ọba 12
12
Joaṣi Ọba Juda
(II. Kro 24:1-16)
1LI ọdun keje Jehu ni Jehoaṣi bẹ̀rẹ si ijọba; ogoji ọdun li o si jọba ni Jerusalemu. Orukọ iyà rẹ̀ a mã jẹ Sibiah ti Beerṣeba.
2Jehoaṣi si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa li ọjọ rẹ̀ gbogbo ninu eyiti Jehoiada alufa nkọ́ ọ.
3Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.
4Jehoaṣi si wi fun awọn alufa pe, Gbogbo owo ti a yà si mimọ́ ti a si mu wá sinu ile Oluwa, ani olukuluku owo ti o kọja, ati owo idiyele olukuluku, ati gbogbo owo ti o ti inu ọkàn olukuluku wá lati mu wá sinu ile Oluwa.
5Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya.
6O si ṣe, li ọdun kẹtalelogun Jehoaṣi ọba, awọn alufa kò iti tun ẹya ile na ṣe.
7Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.
8Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe.
9Ṣugbọn Jehoiada alufa mu apoti kan, o si dá ideri rẹ̀ lu, o si fi i si ẹba pẹpẹ na, li apa ọtún bi ẹnikan ti nwọ̀ inu ile Oluwa lọ: awọn alufa ti o si ntọju iloro na fi gbogbo owo ti a mu wá inu ile Oluwa sinu rẹ̀.
10O si ṣe, nigbati nwọn ri pe, owo pupọ̀ mbẹ ninu apoti na, ni akọwe ọba, ati olori alufa gòke wá, nwọn si dì i sinu apò, nwọn si kà iye owo ti a ri ninu ile Oluwa.
11Nwọn si fi owo na ti a kà le ọwọ awọn ti o nṣiṣẹ na, awọn ti o nṣe abojuto ile Oluwa: nwọn si ná a fun awọn gbẹnagbẹna, ati awọn akọle, ti nṣiṣẹ ile Oluwa.
12Ati fun awọn ọmọle, ati awọn agbẹ́kuta, ati lati rà ìti-igi ati okuta gbígbẹ lati tun ẹya ile Oluwa ṣe, ati fun gbogbo eyi ti a ná fun ile na lati tun u ṣe.
13Ṣugbọn ninu owo ti a mu wá sinu ile Oluwa, a kò fi ṣe ọpọ́n fadakà, alumagàji fitila, awokoto, ipè ohun èlo wura tabi ohun elò fadakà kan fun ile Oluwa:
14Ṣugbọn nwọn fi i fun awọn ti nṣiṣe na, nwọn si fi tun ile Oluwa ṣe.
15Nwọn kò si ba awọn ọkunrin na ṣirò, li ọwọ ẹniti nwọn fi owo na le, lati fi fun awọn ti nṣiṣẹ; nitoriti nwọn ṣe otitọ.
16Owo ẹbọ irekọja ati owo ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni a kò mu wá sinu ile Oluwa: ti awọn alufa ni.
17Nigbana ni Hasaeli ọba Siria gòke lọ, o si ba Gati jà, o si kó o: Hasaeli si doju rẹ̀ kọ ati gòke lọ si Jerusalemu.
18Jehoaṣi ọba Juda si mu gbogbo ohun èlo mimọ́ ti Jehoṣafati, ati Jehoramu, ati Ahasiah awọn baba rẹ̀, awọn ọba Juda ti yà si mimọ́, ati ohun mimọ́ tirẹ̀, ati gbogbo wura ti a ri nibi iṣura ile Oluwa, ati ni ile ọba, o si rán a si Hasaeli ọba Siria: on si lọ kuro ni Jerusalemu.
19Ati iyokù iṣe Joaṣi, ati ohun gbogbo ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
20Awọn iranṣẹ rẹ̀ si dide, nwọn si dì rikiṣi, nwọn si pa Joaṣi ni ile Millo, ti o sọ̀kalẹ lọ si Silla.
21Nitori Josakari ọmọ Simeati ati Jehosabadi ọmọ Ṣomeri, awọn iranṣẹ rẹ̀ pa a, o si kú; nwọn si sìn i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Amasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 12: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.