PẸLUPẸLU, ará, awa nsọ fun nyin niti ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun awọn ijọ Makedonia;
Bi o ti jẹ pe ninu ọpọ idanwò ipọnju, ọ̀pọlọpọ ayọ̀ wọn ati ibu aini wọn di pipọ si ọrọ̀ ilawọ wọn,
Nitori mo jẹri pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, nwọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn,
Nwọn nfi ẹ̀bẹ pipọ rọ̀ wa niti ẹbun ọfẹ yi, ati ti idapọ ninu iṣẹ-iranṣẹ fun awọn enia mimọ́:
Ati eyi, ki iṣe bi awa ti rò rí, ṣugbọn nwọn tètekọ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun;
Tobẹ̃ ti awa fi gba Titu niyanju pe, bi o ti bẹ̀rẹ na, bẹ̃ni ki o si pari ẹbun ọfẹ yi ninu nyin pẹlu.
Ṣugbọn bi ẹnyin ti pọ̀ li ohun gbogbo, ni igbagbọ́, ati ọ̀rọ, ati ìmọ, ati ninu igbiyanjú gbogbo, ati ni ifẹ nyin si wa, ẹ kiyesi ki ẹnyin ki o pọ̀ ninu ẹbun ọfẹ yi pẹlu.
Kì iṣe nipa aṣẹ ni mo fi nsọ, ṣugbọn ki a le ri idi otitọ ifẹ nyin pẹlu, nipa igbiyanjú awọn ẹlomiran.
Nitori ẹnyin mọ̀ ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi on ti jẹ ọlọrọ̀ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ̀ nipa aini rẹ̀.
Ati ninu eyi ni mo fi imọran mi fun nyin: nitori eyi ṣanfani fun nyin, ẹnyin ti o kọ́ bẹrẹ niwọn ọdún ti o kọja, kì iṣe lati ṣe nikan, ṣugbọn lati fẹ́ pẹlu.
Njẹ nisisiyi ẹ pari ṣiṣe na pẹlu; bi imura-tẹlẹ ati ṣe ti wa, bẹni ki ipari si wa lati inu agbara nyin:
Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni.
Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin,
Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà:
Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.