II. Kor 8:1-15

II. Kor 8:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

PẸLUPẸLU, ará, awa nsọ fun nyin niti ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun awọn ijọ Makedonia; Bi o ti jẹ pe ninu ọpọ idanwò ipọnju, ọ̀pọlọpọ ayọ̀ wọn ati ibu aini wọn di pipọ si ọrọ̀ ilawọ wọn, Nitori mo jẹri pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, nwọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn, Nwọn nfi ẹ̀bẹ pipọ rọ̀ wa niti ẹbun ọfẹ yi, ati ti idapọ ninu iṣẹ-iranṣẹ fun awọn enia mimọ́: Ati eyi, ki iṣe bi awa ti rò rí, ṣugbọn nwọn tètekọ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun; Tobẹ̃ ti awa fi gba Titu niyanju pe, bi o ti bẹ̀rẹ na, bẹ̃ni ki o si pari ẹbun ọfẹ yi ninu nyin pẹlu. Ṣugbọn bi ẹnyin ti pọ̀ li ohun gbogbo, ni igbagbọ́, ati ọ̀rọ, ati ìmọ, ati ninu igbiyanjú gbogbo, ati ni ifẹ nyin si wa, ẹ kiyesi ki ẹnyin ki o pọ̀ ninu ẹbun ọfẹ yi pẹlu. Kì iṣe nipa aṣẹ ni mo fi nsọ, ṣugbọn ki a le ri idi otitọ ifẹ nyin pẹlu, nipa igbiyanjú awọn ẹlomiran. Nitori ẹnyin mọ̀ ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi on ti jẹ ọlọrọ̀ rí, ṣugbọn nitori nyin o di talaka, ki a le sọ nyin di ọlọrọ̀ nipa aini rẹ̀. Ati ninu eyi ni mo fi imọran mi fun nyin: nitori eyi ṣanfani fun nyin, ẹnyin ti o kọ́ bẹrẹ niwọn ọdún ti o kọja, kì iṣe lati ṣe nikan, ṣugbọn lati fẹ́ pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ pari ṣiṣe na pẹlu; bi imura-tẹlẹ ati ṣe ti wa, bẹni ki ipari si wa lati inu agbara nyin: Nitori bi imura-tẹlẹ ba wà ṣaju, o jasi itẹwọgbà gẹgẹ bi ohun ti enia bá ni, kì iṣe gẹgẹ bi ohun ti kò ni. Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin, Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà: Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ẹniti o kó pọ̀ju, kò ni nkan le; ẹniti o si kó kere ju, kò ṣe alainito.

II. Kor 8:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ ohun tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti ṣe láàrin àwọn ìjọ Masedonia. Wọ́n ní ọpọlọpọ ìdánwò nípa ìpọ́njú. Sibẹ wọ́n ní ayọ̀ pupọ. Wọ́n ṣe aláìní pupọ, sibẹ wọ́n lawọ́ gan-an. Nítorí mo jẹ́rìí pé wọ́n sa ipá wọn, wọ́n tilẹ̀ ṣe tayọ agbára wọn, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n sì fi ṣe é. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí ni wọ́n fi bẹ̀ wá pé kí á jẹ́ kí àwọn náà lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí fún àwọn onigbagbọ. Wọ́n tilẹ̀ ṣe ju bí a ti lérò lọ, nítorí pé ara wọn pàápàá ni wọ́n kọ́ gbé bùn wá, tí wọ́n sì yọ̀ǹda fún Ọlọrun nípa ìfẹ́ rẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí. Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu. N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní. Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀. Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá, ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó. Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní. Kì í ṣe pé, kí àwọn ẹlòmíràn má ṣe nǹkankan, kí ó jẹ́ pé ẹ̀yin nìkan ni ọrùn yóo wọ̀. Ṣugbọn ọ̀ràn kí ẹ jọ pín in ṣe ní dọ́gba-dọ́gba ni. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ tí ẹ ní yóo mú kí ẹ lè pèsè fún àìní àwọn tí ẹ̀ ń rànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ tí àwọn náà bá ní yóo mú kí wọ́n lè pèsè fún àìní yín. Ọ̀rọ̀ ojuṣaaju kò ní sí níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.”

II. Kor 8:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia; Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnrawọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti pọ̀ lóhùn gbogbo, ní ìgbàgbọ́, àti ọ̀rọ̀ àti ìmọ̀, àti nínú iṣẹ́ ìhìnrere gbogbo, àti ní ìfẹ́ yín sí wa, ẹ rí i wí pé ẹ̀yin pọ̀ sí i nínú ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí pẹ̀lú. Kì í ṣe nípa àṣẹ ni mo fi ń sọ ọ́, ṣùgbọ́n kí a lè rí ìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín pẹ̀lú, nípa iṣẹ́ ìhìnrere ẹlòmíràn. Nítorí ẹ̀yin mọ oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi, pé bí òun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí ṣùgbọ́n nítorí yín ó di tálákà kí a lè sọ yín di ọlọ́rọ̀ nípa àìní rẹ̀. Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín: nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.”