Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ́: nitori ìdapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ si ni pẹlu òkunkun? Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ? Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.
Kà II. Kor 6
Feti si II. Kor 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kor 6:14-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò