Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀? Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀? Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé, “N óo máa gbé ààrin wọn, n óo máa káàkiri ní ààrin wọn. N óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi. Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín.
Kà KỌRINTI KEJI 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KEJI 6:14-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò