II. Kor 13
13
Ìkìlọ̀ Ìgbẹ̀yìn
1EYI li o di igba kẹta ti emi ntọ̀ nyin wá. Li ẹnu ẹlẹri meji tabi mẹta li a o fi idi ọ̀rọ gbogbo mulẹ.
2Mo ti sọ fun nyin ṣaju, mo si nsọ fun nyin tẹlẹ, bi ẹnipe mo wà pẹlu nyin nigba keji, ati bi emi kò ti si lọdọ nyin nisisiyi, mo kọwe si awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ati si gbogbo awọn ẹlomiran, pe bi mo ba tún pada wá, emi kì yio da wọn si:
3Niwọnbi ẹnyin ti nwá àmi Kristi ti nsọ̀rọ ninu mi, ẹniti ki iṣe ailera si nyin, ṣugbọn ti o jẹ agbara ninu nyin.
4Nitoripe a kàn a mọ agbelebu nipa ailera, ṣugbọn on wà lãye nipa agbara Ọlọrun. Nitori awa pẹlu jasi alailera ninu rẹ̀, ṣugbọn awa ó wà lãye pẹlu rẹ̀ nipa agbara Ọlọrun si nyin.
5Ẹ mã wadi ara nyin, bi ẹnyin bá wà ninu igbagbọ́; ẹ mã dan ara nyin wò. Tabi ẹnyin tikaranyin kò mọ̀ ara nyin pe Jesu Kristi wà ninu nyin? afi bi ẹnyin ba jẹ awọn ti a tanù.
6Ṣugbọn mo ni igbẹkẹle pe ẹnyin ó mọ̀ pe, awa kì iṣe awọn ti a tanù.
7Njẹ awa ngbadura si Ọlọrun, ki ẹnyin ki o máṣe ibikibi kan; kì iṣe nitori ki awa ki o le fi ara hàn bi awọn ti a mọ̀ daju, ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mã ṣe eyi ti o dara, bi awa tilẹ dabi awọn ti a tanù.
8Nitori awa kò le ṣe ohun kan lodi si otitọ, bikoṣe fun otitọ.
9Nitori awa nyọ̀, nigbati awa jẹ alailera, ti ẹnyin si jẹ alagbara: eyi li awa si ngbadura fun pẹlu, ani pipe nyin.
10Nitori idi eyi, nigbati emi kò si, mo kọwe nkan wọnyi pe, nigbati mo ba de, ki emi ki o má bã lò ikannú, gẹgẹ bi aṣẹ ti Oluwa ti fifun mi fun idagbasoke, kì si iṣe fun iparun.
Gbolohun Ìdágbére
11Li akotan, ará, odigboṣe. Ẹ jẹ pipé, ẹ tújuka, ẹ jẹ oninu kan, ẹ mã wà li alafia; Ọlọrun ifẹ ati ti alafia yio wà pẹlu nyin.
12Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.
13Gbogbo awọn enia mimọ́ kí nyin.
14Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa, ati ifẹ Ọlọrun, ati ìdapọ ti Ẹmí Mimọ́, ki o wà pẹlu gbogbo nyin. Amin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kor 13: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.