II. Kro 36
36
Joahasi, ọba Juda
(II. A. Ọba 23:30-35)
1NIGBANA ni awọn enia ilẹ na mu Jehoahasi, ọmọ Josiah, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀ ni Jerusalemu.
2Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣu mẹta ni Jerusalemu.
3Ọba Egipti si mu u kuro ni Jerusalemu, o si bù ọgọrun fadakà ati talenti wura kan fun ilẹ na.
4Ọba Egipti si fi Eliakimu, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu; Neko si mu Jehoahasi, arakunrin rẹ̀, o si mu u lọ si Egipti.
Jehoiakimu, Ọba Juda
(II. A. Ọba 23:36—24:7)
5Ẹni ọdun mẹdọgbọn ni Jehoiakimu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu; o si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀,
6Nebukadnessari, ọba Babeli, gòke wá, o si dè e ni ẹ̀won, lati mu u lọ si Babeli.
7Nebukadnessari kó ninu ohun-elo ile Oluwa lọ si Babeli pẹlu, o si fi wọn sinu ãfin rẹ̀ ni Babeli.
8Ati iyokù iṣe Jehoiakimu ati awọn ohun-irira rẹ̀ ti o ti ṣe, ti a si ri ninu rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda: Jehoiakini, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
Jehoiakini, Ọba Juda
(II. A. Ọba 24:8-17)
9Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣù mẹta ati ijọ mẹwa ni Jerusalemu: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.
10Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu.
Sedekaya, Ọba Juda
(II. A. Ọba 24:18-20; Jer 52:1-3a)
11Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu.
12O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Jeremiah, woli, ti o sọ̀rọ lati ẹnu Oluwa wá.
Ìṣubú Jerusalẹmu
(II. A. Ọba 25:1-21; Jer 52:3b-11)
13On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli.
14Pẹlupẹlu, gbogbo awọn olori awọn alufa ati awọn enia dẹṣẹ gidigidi bi gbogbo irira awọn orilẹ-ède, nwọn si sọ ile Oluwa di ẽri, ti on ti yà si mimọ́ ni Jerusalemu.
15Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn si ranṣẹ si wọn lati ọwọ awọn onṣẹ rẹ̀, o ndide ni kùtukutu o si nranṣẹ, nitori ti o ni iyọ́nu si awọn enia rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀.
16Ṣugbọn nwọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, nwọn si kẹgan ọ̀rọ rẹ̀, nwọn si fi awọn woli rẹ̀ ṣẹsin, titi ibinu Oluwa fi ru si awọn enia rẹ̀, ti kò fi si atunṣe.
17Nitorina li o ṣe mu ọba awọn ara Kaldea wá ba wọn, ẹniti o fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn ni ile ibi-mimọ́ wọn, kò si ni iyọ́nu si ọdọmọkunrin tabi wundia, arugbo, tabi ẹniti o bà fun ogbó: on fi gbogbo wọn le e li ọwọ.
18Ati gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun, nla ati kekere, ati iṣura ile Oluwa ati iṣura ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; gbogbo wọn li o mu wá si Babeli.
19Nwọn si kun ile Ọlọrun, nwọn si wó odi Jerusalemu palẹ, nwọn si fi iná sun ãfin rẹ̀, nwọn si fọ́ gbogbo ohun-elo daradara rẹ̀ tũtu.
20Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia:
21Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.
Kirusi Pàṣẹ Pé Kí Àwọn Juu Pada
(Esr 1:1-4)
22Li ọdun kini Kirusi, ọba Persia, ki ọ̀rọ Oluwa lati ẹnu Jeremiah wá ki o le ṣẹ, Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba Persia, soke, ti o si ṣe ikede ni gbogbo ijọba rẹ̀, o si kọ iwe pẹlu, wipe,
23Bayi ni Kirusi, ọba Persia, wi pe, Gbogbo ijọba aiye li Oluwa Ọlọrun fi fun mi, o si ti paṣẹ fun mi lati kọ́ ile kan fun on ni Jerusalemu, ti mbẹ ni Juda. Tani ninu nyin ninu gbogbo awọn enia rẹ̀? Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ki o pẹlu rẹ̀, ki o si gòke lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 36: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.