II. Kro 35
35
Josaya Pa Àjọ Ìrékọjá Mọ́
(II. A. Ọba 23:21-23)
1JOSIAH si pa irekọja kan mọ́ si Oluwa ni Jerusalemu: nwọn si pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù kini.
2O si yàn awọn alufa si iṣẹ wọn, o si gbà wọn ni iyanju si ìsin ile Oluwa.
3O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀;
4Ẹ si mura nipa ile awọn baba nyin, li ẹsẹsẹ nyin, gẹgẹ bi iwe Dafidi, ọba Israeli, ati gẹgẹ bi iwe Solomoni, ọmọ rẹ̀.
5Ẹ si duro ni ibi mimọ́ na, gẹgẹ bi ipin idile awọn baba arakunrin nyin, awọn enia na, ati bi ipin idile awọn ọmọ Lefi.
6Bẹ̃ni ki ẹ pa ẹran irekọja na, ki ẹ si yà ara nyin si mimọ́, ki ẹ si mura fun awọn arakunrin nyin, ki nwọn ki o le mã ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa nipa ọwọ Mose.
7Josiah si fun awọn enia na, ni ọdọ-agutan ati ọmọ ewurẹ, lati inu agbo-ẹran, gbogbo rẹ̀ fun ẹbọ irekọja na, fun gbogbo awọn ti o wà nibẹ, iye rẹ̀ ẹgbã mẹdogun, ati ẹgbẹdogun akọmalu: lati inu ini ọba ni wọnyi.
8Awọn ijoye rẹ̀ si fi tinutinu ta awọn enia li ọrẹ, fun awọn alufa, ati fun awọn ọmọ Lefi: Hilkiah ati Sekariah ati Jehieli, awọn olori ile Ọlọrun, si fun awọn alufa fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹtala ẹran-ọ̀sin kekeke, ati ọ̃dunrun malu.
9Koniah ati Ṣemaiah ati Netaneeli, awọn arakunrin rẹ̀, ati Hasabiah ati Jehieli ati Josabadi, olori awọn ọmọ Lefi, si fun awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ irekọja na ni ẹgbẹdọgbọn ọdọ-agutan, ati ẹ̃dẹgbẹta malu.
10Bẹ̃li a si mura ìsin na, awọn alufa si duro ni ipò wọn, ati awọn ọmọ Lefi ni ipa iṣẹ wọn gẹgẹ bi aṣẹ ọba.
11Awọn ọmọ Lefi si pa ẹran irekọja na, awọn alufa si wọ́n ẹ̀jẹ na lati ọwọ wọn wá, awọn ọmọ Lefi si bó wọn.
12Nwọn si yà awọn ẹbọ-sisun sapakan, ki nwọn ki o le pin wọn funni gẹgẹ bi ipin idile awọn enia, lati rubọ si Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose. Bẹ̃ni nwọn si ṣe awọn malu pelu.
13Nwọn si fi iná sun irekọja na gẹgẹ bi ilana na: ṣugbọn awọn ẹbọ mimọ́ iyokù ni nwọn bọ̀ ninu ìkoko, ati ninu òdu ati ninu agbada, nwọn si pin i kankan fun gbogbo enia.
14Lẹhin na nwọn mura silẹ fun ara wọn, ati fun awọn alufa; nitoriti awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, wà ni riru ẹbọ sisun ati ọ̀ra titi di alẹ; nitorina awọn ọmọ Lefi mura silẹ fun ara wọn ati fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni.
15Awọn akọrin, awọn ọmọ Asafu duro ni ipò wọn, gẹgẹ bi ofin Dafidi, ati ti Asafu, ati ti Hemani, ati ti Jedutuni, ariran ọba; awọn adèna si duro ni olukuluku ẹnu-ọ̀na; nwọn kò gbọdọ lọ kuro li ọ̀na-iṣẹ wọn, nitoriti awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi, ti mura silẹ dè wọn.
16Bẹ̃ni a si mura gbogbo ìsin Oluwa li ọjọ kanna, lati pa irekọja mọ́, ati lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ Oluwa, gẹgẹ bi ofin Josiah, ọba.
17Ati awọn ọmọ Israeli ti a ri nibẹ, pa irekọja na mọ́ li akoko na, ati ajọ aiwukara li ọjọ meje.
18Kò si si irekọja kan ti o dabi rẹ̀ ti a ṣe ni Israeli lati igba ọjọ Samueli woli; bẹ̃ni gbogbo awọn ọba Israeli kò pa iru irekọja bẹ̃ mọ́, bi eyi ti Josiah ṣe, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Juda ati Israeli ti a ri nibẹ, ati awọn ti ngbe Jerusalemu.
19Li ọdun kejidilogun ijọba Josiah li a pa irekọja yi mọ́.
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya
(II. A. Ọba 23:28-30)
20Lẹhin gbogbo eyi, ti Josiah ti tun ile na ṣe tan, Neko, ọba Egipti, gòke wá, si Karkemiṣi lẹba odò Euferate: Josiah si jade tọ̀ ọ.
21Ṣugbọn o rán ikọ̀ si i, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, iwọ ọba Juda? Emi kò tọ̀ ọ wá loni, bikòṣe si ile ti mo ba ni ijà: Ọlọrun sa pa aṣẹ fun mi lati yara: kuro lọdọ Ọlọrun, ẹniti o wà pẹlu mi, ki on má ba pa ọ run.
22Ṣugbọn Josiah kò yi oju rẹ̀ pada kuro lọdọ rẹ̀, ṣugbọn o pa aṣọ ara rẹ dà, ki o le ba a jà, kò si fi eti si ọ̀rọ Neko lati ẹnu Ọlọrun wá, o si wá ijagun li àfonifoji Megiddo.
23Awọn tafatafa si ta Josiah, ọba: ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ gbé mi kuro; nitoriti mo gbà ọgbẹ gidigidi.
24Nitorina awọn iranṣẹ rẹ̀ gbé e kuro ninu kẹkẹ́ na, nwọn si fi i sinu kẹkẹ́ rẹ̀ keji; nwọn si mu u wá si Jerusalemu, o si kú, a si sìn i ninu ọkan ninu awọn iboji awọn baba rẹ̀. Gbogbo Juda ati Jerusalemu si ṣọ̀fọ Josiah.
25Jeremiah si pohùn rere ẹkún fun Josiah, ati gbogbo awọn akọrin ọkunrin, ati awọn akọrin obinrin, si nsọ ti Josiah ninu orin-ẹkún wọn titi di oni yi, nwọn si sọ wọn di àṣa kan ni Israeli; si kiyesi i, a kọ wọn ninu awọn orin-ẹkún.
26Ati iyokú iṣe Josiah, ati ìwa rere rẹ̀, gẹgẹ bi eyiti a ti kọ ninu ofin Oluwa,
27Ati iṣe rẹ̀, ti iṣaju ati ti ikẹhin, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Judah.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 35: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.