II. Kro 15

15
Asa Ṣe Àtúnṣe
1ẸMI Ọlọrun si wá si ara Asariah, ọmọ Odedi:
2O si jade lọ ipade Asa, o si wi fun u pe, Ẹ gbọ́ temi, Asa, ati gbogbo Juda ati Benjamini! Oluwa pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rẹ̀, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀ ọ, on o si kọ̀ nyin.
3Njẹ ọjọ pupọ ni Israeli ti wà laisìn Ọlọrun otitọ, ati laini alufa ti nkọni, ati laini ofin.
4Ṣugbọn nwọn yipada si Oluwa. Ọlọrun Israeli, ninu wahala wọn, nwọn si ṣe awari rẹ̀, nwọn si ri i.
5Ati li ọjọ wọnni alafia kò si fun ẹniti o njade, tabi fun ẹniti nwọle, ṣugbọn ibanujẹ pupọ li o wà lori gbogbo awọn olugbe ilẹ wọnni.
6Orilẹ-ède si kọlù orilẹ-ède, ati ilu si ilu: nitori ti Ọlọrun fi oniruru ipọnju bà wọn ninu jẹ.
7Ṣugbọn ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ ọwọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ère.
8Nigbati Asa gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ati asọtẹlẹ Odedi woli, o mu ara le, o si mu awọn ohun irira kuro lati inu gbo-gbo ilẹ Juda ati Benjamini, ati lati inu ilu ti o ti gbà lati oke Efraimu, o si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, ti o wà niwaju iloro Oluwa.
9O si kó gbogbo Juda ati Benjamini jọ, ati awọn alejo ti o pẹlu wọn lati inu Efraimu ati Manasse, ati lati inu Simeoni wá: nitori ti nwọn ya li ọ̀pọlọpọ sọdọ rẹ̀ lati inu Israeli wá, nigbati nwọn ri pe, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.
10Bẹ̃ni nwọn kó ara wọn jọ si Jerusalemu, li oṣù kẹta, li ọdun kẹdogun ijọba Asa.
11Nwọn si fi ninu ikógun ti nwọn kó wá, rubọ si Oluwa li ọjọ na, ẹ̃dẹgbãrin akọ-malu ati ẹ̃dẹgbãrin agutan.
12Nwọn si tun dá majẹmu lati wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, tinutinu wọn ati tọkàntọkàn wọn.
13Pe, ẹnikẹni ti kò ba wá Oluwa Ọlọrun Israeli, pipa li a o pa a, lati ẹni-kekere de ẹni-nla, ati ọkunrin ati obinrin.
14Nwọn si fi ohùn rara bura fun Oluwa, ati pẹlu ariwo, ati pẹlu ipè ati pẹlu fère.
15Gbogbo Juda si yọ̀ si ibura na: nitoriti nwọn fi tinu-tinu wọn bura, nwọn si fi gbogbo ifẹ inu wọn wá a; nwọn si ri i: Oluwa si fun wọn ni isimi yikakiri.
16Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni.
17Ṣugbọn a kò mu ibi giga wọnni kuro ni Israeli: kiki ọkàn Asa wà ni pipé li ọjọ rẹ̀ gbogbo.
18O si mu ohun mimọ́ wọnni ti baba rẹ̀, ati ohun mimọ́ wọnni ti on tikararẹ̀ wá sinu ile Ọlọrun, fadakà, wura, ati ohun-elo wọnni.
19Ogun kò si mọ titi di ọdun karundilogoji ọba Asa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀