II. Kro 16

16
Ìyọnu De bá Israẹli
(I. A. Ọba 15:17-22)
1LI ọdun kẹrindilogoji ijọba Asa, Baaṣa, ọba Israeli, gòke wá si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má ba jẹ ki ẹnikan ki o jade, tabi ki o wọle tọ̀ Asa, ọba Juda lọ.
2Nigbana ni Asa mu fadakà ati wura jade lati inu iṣura ile Oluwa wá, ati ile ọba, o si ranṣẹ si Benhadadi, ọba Siria, ti ngbe Damasku, wipe,
3Majẹmu kan wà larin temi tirẹ, bi o ti wà lãrin baba mi ati baba rẹ; kiyesi i, mo fi fadakà ati wura ranṣẹ si ọ; lọ, bà majẹmu ti o ba Baaṣa, ọba Israeli dá jẹ, ki o le lọ kuro lọdọ mi.
4Benhadadi si gbọ́ ti Asa ọba, o si rán awọn olori ogun rẹ̀ si ilu Israeli wọnni, nwọn si kọlù Ijoni, ati Dani, ati Abel-Maimu, ati gbogbo ilu iṣura Naftali.
5O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o ṣiwọ atikọ́ Rama, o si dá iṣẹ rẹ̀ duro.
6Ṣugbọn Asa ọba kó gbogbo Juda jọ; nwọn si kó okuta ati igi Rama lọ, eyiti Baaṣa nfi kọ́le; o si fi kọ́ Geba ati Mispa.
Wolii Hanani
7Li àkoko na Hanani, ariran, wá sọdọ Asa, ọba Juda, o si wi fun u pe, Nitoriti iwọ gbẹkẹle ọba Siria, iwọ kò si gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun rẹ, nitorina ni ogun ọba Siria ṣe bọ́ lọwọ rẹ.
8Awọn ara Etiopia ati awọn ara Libia kì iha ise ogun nla, pẹlu ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin? ṣugbọn nitoriti iwọ gbẹkẹle Oluwa, on fi wọn le ọ lọwọ.
9Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà.
10Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na.
Òpin Ìjọba Asa
(I. A. Ọba 15:23-24)
11Si kiyesi i, iṣe Asa ti iṣaju ati ti ikẹhin, wò o, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.
12Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun.
13Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, o si kú li ọdun kọkanlelogoji ijọba rẹ̀.
14Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Kro 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀