II. Kro 14
14
Asa Ọba Ṣẹgun Àwọn Ará Sudani
1Bẹ̃ni Abijah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Asa ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Li ọjọ rẹ̀, ilẹ na wà li alafia li ọdun mẹwa.
2Asa si ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
3Nitori ti o mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, ati ibi giga wọnni, o si wó awọn ere palẹ, o si bẹ ere-oriṣa wọn lulẹ:
4O si paṣẹ fun Juda lati ma wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, ati lati ma pa aṣẹ ati ofin rẹ̀ mọ́.
5O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀.
6O si kọ́ ilu olodi wọnni ni Juda, nitoriti ilẹ na ni isimi, on kò si ni ogun li ọdun wọnni; nitori Oluwa ti fun wọn ni isimi.
7O si sọ fun Juda pe, Ẹ jẹ ki a kọ́ ilu wọnni, ki a si mọdi yi wọn ka, ati ile-iṣọ, ilẹkun ati ọpa-idabu, nigbati ilẹ na si wà niwaju wa, nitori ti awa ti wá Oluwa Ọlọrun wa, awa ti wá a, on si ti fun wa ni isimi yikakiri. Bẹ̃ni nwọn kọ́ wọn, nwọn si ṣe rere.
8Asa si ni ogun ti ngbé asà ati ọ̀kọ, ọkẹ mẹdogun lati inu Juda wá, ati lati inu Benjamini wá, ọkẹ mẹrinla ti ngbé apata ati ti nfa ọrun: gbogbo wọnyi si ni akọni ogun.
9Sera, ara Etiopia, si jade si wọn, pẹlu ãdọta ọkẹ enia, ati ọ̃dunrun kẹkẹ́; nwọn wá si Mareṣa.
10Asa si jade tọ̀ ọ, nwọn si tẹ ogun li afonifoji Sefata lẹba Mareṣa.
11Asa si ke pe Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, Oluwa! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ràn alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, Oluwa Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹ le ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọ̀pọlọpọ yi lọ, Oluwa, iwọ li Ọlọrun wa; máṣe jẹ ki enia ki o bori rẹ,
12Bẹ̃li Oluwa kọlù awọn ara Etiopia niwaju Asa, ati niwaju Juda: awọn ara Etiopia si sa.
13Ati Asa ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ lepa wọn de Gerari: a si bi awọn ara Etiopia ṣubu ti ẹnikan kò tun wà li ãye; nitori ti a ṣẹ́ wọn niwaju Oluwa ati niwaju ogun rẹ̀; nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ikogun lọ.
14Nwọn si kọlu gbogbo ilu yikakiri Gerari: nitori ti ẹ̀ru Oluwa bà wọn, nwọn si kó gbogbo ilu na, nitori ikógun pọ̀ rekọja ninu wọn.
15Nwọn si kọlù awọn agbo-ẹran-ọsin, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ agutan ati ibakasiẹ lọ, nwọn si pada wá si Jerusalemu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 14: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.