I. Sam Ọ̀rọ̀ Iṣaájú
Ọ̀rọ̀ Iṣaájú
Kókó ohun tí ó wà ninu Ìwé Kìn-in-ni ti Samuẹli ni àkọsílẹ̀ àyípadà ètò ìjọba Israẹli, láti ìjọba Àwọn Onídàájọ́ sí ìjọba tí àwọn ọba gidi jẹ́ olórí ati aláṣẹ ìlú. Àwọn eniyan mẹta pataki ni àyípadà yìí kàn gbọ̀ngbọ̀n. Àyípadà ìjọba yìí ṣẹlẹ̀ ní àkókò Samuẹli, òun ni ó jẹ oyè onídàájọ́ kẹ́yìn ní Israẹli. Ẹnìkejì ni Saulu; òun ni ọba tí ó kọ́kọ́ jẹ ní ilẹ̀ Israẹli. Dafidi ni ẹni kẹta. Ó rí ọpọlọpọ ìrírí nípa àwọn nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ lákòókò Samuẹli ati Saulu, kí ìjọba rẹ̀ tó fi ìdí múlẹ̀.
Ní ṣókí, ohun tí ìwé yìí ń sọ, gẹ́gẹ́ bíi ti inú àwọn ìwé ìtàn Majẹmu Laelae yòókù ni pé, títẹ̀lé àṣẹ Ọlọrun a máa kó ire bá eniyan; ṣùgbọ́n ìjìyà ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ ati lílòdì sí àṣẹ Ọlọrun. Èyí hàn ketekete ninu iṣẹ́ tí OLUWA rán sí wolii Eli ní orí 2 ẹsẹ 30, pé, “N ó buyì fún ẹni tí ó bá buyì fún mi, n ó sì kọ ẹni tí ó bá kọ̀ mí sílẹ̀.”
Ìwé yìí ṣe àkọsílẹ̀ ire ati ibi tí ó wà ninu yíyan ọba fún àwọn ọmọ Israẹli. OLUWA ni Ọba lórí wọn tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí wọn béèrè fún ọba láàrin ara wọn, OLUWA yàn án fún wọn. Ohun tí ó ṣe pataki jù ni pé, ati ọba tí wọ́n yàn ati àwọn ọmọ Israẹli yòókù, Ọlọrun ni aláṣẹ ati onídàájọ́ lórí gbogbo wọn (2:7-10). Ní abẹ́ òfin Ọlọrun, gbogbo eniyan pátá, ati ọlọ́rọ̀ ati talaka, ọ̀kan náà ni wọ́n, olukuluku ni ó sì ní ẹ̀tọ́ tirẹ̀, láìsí ìrẹ́jẹ.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Samuẹli gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ ní Israẹli 1:1—7:17
Saulu jọba 8:1—10:27
Àwọn ọdún tí Saulu kọ́kọ́ lò lórí oyè 11:1—15:35
Dafidi ati Saulu 16:1—30:31
Ikú Saulu ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin 31:1-13
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam Ọ̀rọ̀ Iṣaájú: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.