I. Sam 1

1
Ẹlkana ati Ìdílé Rẹ̀ ní Ìlú Ṣilo
1NIGBANA ọkunrin kan wà, ara Ramataim-sofimu, li oke Efraimu, orukọ rẹ̀ ama jẹ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ara Efrata.
2O si ni aya meji; orukọ ekini ama jẹ Hanna, orukọ ekeji a si ma jẹ Peninna: Peninna si bimọ, ṣugbọn Hanna kò bi.
3Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọdun lati sìn ati lati ṣe irubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ọmọ Eli mejeji Hofni ati Finehasi alufa Oluwa, si wà nibẹ.
4Nigbati o si di akoko ti Elkana ṣe irubọ, o fi ipin fun Peninna aya rẹ̀, ati fun gbogbo ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ obinrin.
5Ṣugbọn Hanna li on fi ipin ẹni meji fun; nitori ti o fẹ Hanna: ṣugbọn Oluwa ti se e ni inu.
6Orogún rẹ̀ pẹlu a si ma tọ́ ọ gidigidi lati mu u binu, nitoriti Oluwa ti se e ni inu.
7Bi on iti ma ṣe bẹ̃ lọdọdun, nigbati Hanna ba goke lọ si ile Oluwa, bẹni Peninna ima bà a ni inu jẹ; nitorina ama sọkun, kò si jẹun.
8Nigbana ni Elkana ọkọ rẹ̀ si sọ fun u pe, Hanna, ẽṣe ti iwọ nsọkun? ẽṣe ti iwọ kò si jẹun? ẽsi ti ṣe ti inu rẹ fi bajẹ? emi ko ha sàn fun ọ ju ọmọ mẹwa lọ bi?
Hana ati Eli
9Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa.
10On si wà ninu ibinujẹ ọkàn, o si mbẹ Oluwa, o si sọkun gidigidi.
11On si jẹ́'jẹ, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ nitõtọ ba bojuwo ipọnju iranṣẹbinrin rẹ, ti o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn bi iwọ ba fi ọmọkunrin kan fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi i fun Oluwa ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, abẹ kì yio si kàn a lori.
12O si ṣe bi o ti mbẹbẹ sibẹ niwaju Oluwa, bẹ̃ni Eli kiyesi ẹnu rẹ̀.
13Njẹ Hanna, on nsọ̀rọ li ọkàn rẹ̀; kiki etè rẹ̀ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ́ ohùn rẹ̀: nitorina ni Eli fi rò pe, o mu ọti-waini yó.
14Eli si wi fun u pe, Iwọ o ti mu ọti-waini pẹ to? mu ọti-waini rẹ kuro lọdọ rẹ.
15Hanna si dahun wipe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, emi li obinrin oniròbinujẹ ọkàn: emi kò mu ọti-waini tabi ọti lile, ṣugbọn ọkàn mi li emi ntú jade niwaju Oluwa.
16Má ṣe ka iranṣẹbinrin rẹ si ọmọbinrin Beliali: nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ irò ati ibinujẹ inu mi ni mo ti nsọ disisiyi.
17Nigbana ni Eli dahun o si wipe, Ma lọ li alafia: ki Ọlọrun Israeli ki o fi idahun ibere ti iwọ bere lọdọ rẹ̀ fun ọ.
18On si wipe, Ki iranṣẹbinrin rẹ ki o ri ore-ọfẹ loju rẹ. Bẹ̃li obinrin na ba tirẹ̀ lọ, o si jẹun, ko si fà oju ro mọ.
Ìbí Samuẹli ati Ìyàsímímọ́ Rẹ̀
19Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn wolẹ sìn niwaju Oluwa, nwọn pada wá si ile wọn si Rama: Elkana si mọ aya rẹ̀; Oluwa si ranti rẹ̀.
20Nitorina, o si ṣe, nigbati ọjọ rẹ̀ pe lẹhin igbati Hanna loyun, o si bi ọmọkunrin kan, o si pe orukọ rẹ̀ ni Samueli, pe, Nitoriti mo bere rẹ̀ lọwọ Oluwa.
21Ọkunrin na Elkana, ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀, goke lọ lati rubọ ọdun si Oluwa, ati lati san ileri ifẹ rẹ̀.
22Ṣugbọn Hanna ko goke lọ; nitori ti o wi fun ọkọ rẹ̀ pe, o di igbati mo ba gba ọmu lẹnu ọmọ na, nigbana li emi o mu u lọ, ki on ki o le fi ara han niwaju Oluwa, ki o si ma gbe ibẹ titi lai.
23Elkana ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ṣe eyi ti o tọ li oju rẹ; duro titi iwọ o fi gba ọmu li ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ki Oluwa ki o sa mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ. Bẹ̃li obinrin na si joko, o si fi ọmu fun ọmọ rẹ̀ titi o fi gbà a lẹnu rẹ̀.
24Nigbati o si gba ọmu li ẹnu rẹ̀, o si mu u goke lọ pẹlu ara rẹ̀, pẹlu ẹgbọrọ malu mẹta, ati iyẹfun efa kan, ati igo ọti-wain kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọmọde.
25Nwọn pa ẹgbọrọ malu, nwọn si mu ọmọ na tọ̀ Eli wá.
26Hanna si wipe, oluwa mi, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, oluwa mi, emi li obinrin na ti o duro li ẹba ọdọ rẹ nihin ti ntọrọ lọdọ Oluwa.
27Ọmọ yi ni mo ntọrọ; Oluwa si fi idahun ibere ti mo bere lọdọ rẹ̀ fun mi:
28Nitorina pẹlu emi fi i fun Oluwa; ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀: nitoriti mo ti bere rẹ̀ fun Oluwa. Nwọn si wolẹ-sin Oluwa nibẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀