I. Sam 20

20
Jonatani Ran Dafidi lọ́wọ́
1DAFIDI si sa kuro ni Naoti ti Rama, o si wá, o si wi li oju Jonatani pe, Kili emi ṣe? kini ìwa buburu mi, ati kili ẹ̀ṣẹ mi li oju baba rẹ, ti o fi nwá ọ̀na ati pa mi.
2On si wi fun u pe, Ki a má ri i, iwọ kì yio kú: wõ, baba mi ki yio ṣe nkan nla tabi kekere lai sọ ọ li eti mi, njẹ, esi ti ṣe ti baba mi yio fi pa nkan yi mọ fun mi? nkan na kò ri bẹ̃.
3Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú.
4Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ, wi, emi o si ṣe e fun ọ.
5Dafidi si wi fun Jonatani pe, Wõ, li ọla li oṣu titun, emi kò si gbọdọ ṣe alai ba ọba joko lati jẹun; ṣugbọn jẹ ki emi ki o lọ, ki emi si fi ara pamọ li oko titi yio fi di aṣalẹ ijọ kẹta.
6Bi o ba si ṣepe baba rẹ fẹ mi kù, ki o si wi fun u pe, Dafidi bẹ̀ mi lati sure lọ si Betlehemu ilu rẹ̀: nitoripe ẹbọ ọdun kan kò nibẹ fun gbogbo idile na.
7Bi o ba wipe, O dara, alafia mbẹ fun iranṣẹ rẹ: ṣugbọn bi o ba binu pupọ, njẹ ki iwọ ki o mọ̀ daju pe buburu ni o nrò ninu rẹ̀.
8Iwọ o si ṣe ore fun iranṣẹ rẹ, nitoripe iwọ ti mu iranṣẹ rẹ wọ inu majẹmu Oluwa pẹlu rẹ; ṣugbọn bi ìwa buburu ba mbẹ li ọwọ mi, iwọ tikararẹ pa mi; ẽṣe ti iwọ o fi mu mi tọ baba rẹ lọ?
9Jonatani si wipe, Ki eyini ki o jina si ọ: nitoripe bi emi ba mọ̀ daju pe baba mi npete ibi ti yio wá sori rẹ, njẹ emi le iṣe alaisọ ọ fun ọ bi?
10Nigbana ni Dafidi wi fun Jonatani pe, Tani yio sọ fun mi? tabi yio ti ri bi baba rẹ ba si fi ìjãnu da ọ lohùn.
11Jonatani si wi fun Dafidi pe, Wá, jẹ ki a jade lọ si pápá. Awọn mejeji si jade lọ si pápá.
12Jonatani si wi fun Dafidi pe, Oluwa Ọlọrun Israeli, nigbati mo ba si lu baba mi li ohùn gbọ́ li ọla tabi li ọtunla, si wõ, bi ire ba wà fun Dafidi, ti emi kò ba si ranṣẹ si ọ, ti emi kò si sọ ọ li eti rẹ.
13Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi.
14Ki iṣe kiki igbà ti mo wà lãye ni iwọ o si ṣe ãnu Oluwa fun mi, ki emi ki o má kú.
15Ṣugbọn ki iwọ ki o máṣe mu ãnu rẹ kuro ni ile mi lailai: ki isi ṣe igbati Oluwa ke olukuluku ọtá Dafidi kuro lori ilẹ.
16Bẹ̃ ni Jonatani bá ile Dafidi da majẹmu wipe, Oluwa yio si bere rẹ̀ lọwọ awọn ọta Dafidi.
17Jonatani si tun mu ki Dafidi ki o bura nitoriti o sa fẹ ẹ: o si fẹ ẹ bi o ti fẹ ẹmi ara rẹ̀.
18Nigbana ni Jonatani wi fun Dafidi pe, ọla li oṣu titun: a o si fẹ ọ kù, nitoriti ipò rẹ yio ṣofo.
19Bi iwọ ba si duro ni ijọ mẹta, nigbana ni iwọ o si yara sọkalẹ, iwọ o si wá si ibiti iwọ gbe ti fi ara rẹ pamọ si nigbati iṣẹ na wà lọwọ, iwọ o si joko ni ibi okuta Eseli.
20Emi o si ta ọfà mẹta si ìha ibẹ̀ na, gẹgẹ bi ẹnipe mo ta si àmi kan.
21Si wõ, emi o ran ọmọde-kọnrin kan pe, Lọ, ki o si wá ọfa wọnni. Bi emi ba tẹnu mọ ọ fun ọmọkunrin na, pe, Wõ, ọfa wọnni wà lẹhin rẹ, ṣà wọn wá; nigbana ni iwọ o ma bọ̀; nitoriti alafia mbẹ fun ọ, kò si ewu; bi Oluwa ti wà.
22Ṣugbọn bi emi ba wi bayi fun ọmọde-kọnrin na pe, Wõ ọfa na mbẹ niwaju rẹ; njẹ ma ba tirẹ lọ; Oluwa li o rán ọ lọ.
23Niti ọ̀rọ ti emi ati iwọ si ti jumọ sọ, wõ, ki Oluwa ki o wà larin iwọ ati emi titi lailai.
24Bẹ̃ni Dafidi sì pa ara rẹ̀ mọ li oko; nigbati oṣu titun si de, ọba si joko lati jẹun.
25Ọba si joko ni ipò rẹ̀ bi igba atijọ lori ijoko ti o gbe ogiri; Jonatani si dide, Abneri si joko ti Saulu, ipò Dafidi si ṣofo.
26Ṣugbọn Saulu kò sọ nkan nijọ na; nitoriti on rò pe, Nkan ṣe e ni, on ṣe alaimọ́ ni; nitotọ o ṣe alaimọ́ ni.
27O si ṣe, ni ijọ keji, ti o jẹ ijọ keji oṣu, ipò Dafidi si ṣofo; Saulu si wi fun Jonatani ọmọ rẹ̀ pe, Ẽṣe ti ọmọ Jesse ko fi wá si ibi onjẹ lana ati loni?
28Jonatani si da Saulu lohùn pe, Dafidi bẹ̀ mi lati lọ si Betlehemu:
29O si wipe, Jọwọ, jẹ ki emi ki o lọ; nitoripe idile wa li ẹbọ kan iru ni ilu na; ẹgbọn mi si paṣẹ fun mi pe ki emi ki o má ṣaiwà nibẹ; njẹ, bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ rẹ, jọwọ, jẹ ki emi lọ, ki emi ri awọn ẹgbọn mi. Nitorina ni ko ṣe wá si ibi onjẹ ọba.
30Ibinu Saulu si fà ru si Jonatani, o si wi fun u pe, Iwọ ọmọ ọlọtẹ buburu yi, ṣe emi mọ̀ pe, iwọ ti yàn ọmọ Jesse fun itiju rẹ, ati fun itiju ihoho iya rẹ?
31Nitoripe ni gbogbo ọjọ ti ọmọ Jesse wà lãye li orilẹ, iwọ ati ijọba rẹ kì yio duro. Njẹ nisisiyi, ranṣẹ ki o si mu u fun mi wá, nitoripe yio kú dandan.
32Jonatani si da Saulu baba rẹ̀ lohùn, o si wi fun u pe, Nitori kini on o ṣe kú? kili ohun ti o ṣe?
33Saulu si jù ẹṣín si i lati fi pa a; Jonatani si wa mọ̀ pe baba on ti pinnu rẹ̀ lati pa Dafidi.
34Bẹ̃ni Jonatani sì fi ibinu dide kuro ni ibi onjẹ, kò si jẹn ní ijọ keji oṣu na: inu rẹ̀ si bajẹ gidigidi fun Dafidi, nitoripe baba rẹ̀ doju tì i.
35O si ṣe, li owurọ ni Jonatani jade lọ si oko li akoko ti on ati Dafidi ti fi si, ọmọdekunrin kan si wà pẹlu rẹ̀.
36O si wi fun ọmọdekunrin rẹ̀ pe, sare, ki o si wá ọfà wọnni ti emi o ta. Bi ọmọde na si ti nsare, on si tafa rekọja rẹ̀.
37Nigbati ọmọdekunrin na si de ibi ọfà ti Jonatani ta, Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na, o si wipe, ọfà na ko ha wà niwaju rẹ bi?
38Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na pe, Sare, yara, máṣe duro. Ọmọdekunrin Jonatani si ṣa ọfà wọnni, o si tọ̀ oluwa rẹ̀ wá.
39Ọmọdekunrin na kò si mọ̀ nkan: ṣugbọn Jonatani ati Dafidi li o mọ̀ ọ̀ran na.
40Jonatani si fi apó ati ọrun rẹ̀ fun ọmọdekunrin rẹ̀, o si wi fun u pe, Lọ, ki o si mu wọn lọ si ilu.
41Bi ọmọdekunrin na ti lọ tan, Dafidi si dide lati iha gusu, o si wolẹ, o si tẹriba lẹrinmẹta: nwọn si fi ẹnu ko ara wọn li ẹnu, nwọn si jumọ sọkun, ekini keji wọn, titi Dafidi fi bori.
42Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ma lọ li alafia, bi o ti jẹ pe awa mejeji ti jumọ bura li orukọ Oluwa, pe, Ki Oluwa ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin iru-ọmọ mi ati lãrin iru-ọmọ rẹ lailai. On si dide, o si lọ kuro: Jonatani si lọ si ilu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 20: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀