I. Sam 19

19
Saulu fẹ́ pa Dafidi
1SAULU si sọ fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o pa Dafidi.
2Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ.
3Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ.
4Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ.
5Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ?
6Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a.
7Jonatani si pe Dafidi, Jonatani si ro gbogbo ọràn na fun u. Jonatani si mu Dafidi tọ Saulu wá, on si wà niwaju rẹ̀, bi igbà atijọ.
8Ogun si tun wà sibẹ, Dafidi si jade lọ, o si ba awọn Filistini jà, o si pa wọn pupọ; nwọn si sa niwaju rẹ̀.
9Ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa wá si bà le Saulu, o si joko ni ile rẹ̀ ton ti ẹṣín rẹ̀ li lọwọ rẹ̀: Dafidi a si ma fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru.
10Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.
11Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ.
12Mikali si sọ Dafidi kalẹ lati oju ferese kan wá; on si lọ, o sa, o si fi ara rẹ̀ pamọ.
13Mikali si mu ere, o si tẹ́ ẹ sori akete, o si fi timtim onirun ewurẹ sibẹ fun irọri rẹ̀, o si fi aṣọ bò o.
14Nigbati Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi, on si wi fun wọn pe, Kò sàn.
15Saulu si tun ran awọn onṣẹ na lọ iwo Dafidi, o wi pe, Gbe e goke tọ̀ mi wá ti-akete ti-akete ki emi ki o pa a.
16Nigbati awọn onṣẹ na de, sa wõ, ere li o si wà lori akete, ati timtim onirun ewurẹ fun irọri rẹ̀.
17Saulu si wi fun Mikali pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi tàn mi jẹ bẹ̃, ti iwọ si fi jọwọ ọta mi lọwọ lọ, ti on si bọ? Mikali si da Saulu lohùn pe, On wi fun mi pe, Jẹ ki emi lọ; ẽṣe ti emi o fi pa ọ?
18Dafidi si sa, o si bọ, o si tọ Samueli wá ni Rama, o si rò fun u gbogbo eyi ti Saulu ṣe si i. On ati Samueli si lọ, nwọn si ngbe Naoti.
19A si wi fun Saulu pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni Naoti ni Rama.
20Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi: nigbati nwọn ri ẹgbẹ awọn wolĩ ti nsọtẹlẹ, ati Samueli ti o duro bi olori wọn, Ẹmi Ọlọrun si bà le awọn onṣẹ Saulu, awọn na si nsọtẹlẹ.
21A si ro fun Saulu, o si ran onṣẹ miran, awọn na si nsọtẹlẹ. Saulu si tun ran onṣẹ lẹ̃kẹta, awọn na si nsọtẹlẹ.
22On na si lọ si Rama, o si de ibi kanga nla kan ti o wà ni Seku: o si bere, o si wipe, Nibo ni Samueli ati Dafidi gbe wà? ẹnikan si wipe, Wõ, nwọn mbẹ ni Naoti ni Rama.
23On si lọ sibẹ si Naoti ni Rama: Ẹmi Ọlọrun si ba le on na pẹlu, o si nlọ, o si nsọtẹlẹ titi o fi de Naoti ni Rama.
24On si bọ aṣọ rẹ̀ silẹ, o si sọtẹlẹ pẹlu niwaju Samueli, o si dubulẹ nihoho ni gbogbo ọjọ na, ati ni gbogbo oru na. Nitorina nwọn si wipe, Saulu pẹlu ha wà ninu awọn woli?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 19: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀