O si ṣe bi o ti mbẹbẹ sibẹ niwaju Oluwa, bẹ̃ni Eli kiyesi ẹnu rẹ̀. Njẹ Hanna, on nsọ̀rọ li ọkàn rẹ̀; kiki etè rẹ̀ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ́ ohùn rẹ̀: nitorina ni Eli fi rò pe, o mu ọti-waini yó. Eli si wi fun u pe, Iwọ o ti mu ọti-waini pẹ to? mu ọti-waini rẹ kuro lọdọ rẹ. Hanna si dahun wipe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, emi li obinrin oniròbinujẹ ọkàn: emi kò mu ọti-waini tabi ọti lile, ṣugbọn ọkàn mi li emi ntú jade niwaju Oluwa. Má ṣe ka iranṣẹbinrin rẹ si ọmọbinrin Beliali: nitoripe ninu ọ̀pọlọpọ irò ati ibinujẹ inu mi ni mo ti nsọ disisiyi. Nigbana ni Eli dahun o si wipe, Ma lọ li alafia: ki Ọlọrun Israeli ki o fi idahun ibere ti iwọ bere lọdọ rẹ̀ fun ọ. On si wipe, Ki iranṣẹbinrin rẹ ki o ri ore-ọfẹ loju rẹ. Bẹ̃li obinrin na ba tirẹ̀ lọ, o si jẹun, ko si fà oju ro mọ.
Kà I. Sam 1
Feti si I. Sam 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Sam 1:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò