I. A. Ọba 17
17
Elija ati Ọ̀dá
1ELIJAH ara Tiṣbi, lati inu awọn olugbe Gileadi, wi fun Ahabu pe, Bi Oluwa Ọlọrun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, kì yio si ìri tabi òjo li ọdun wọnyi, ṣugbọn gẹgẹ bi ọ̀rọ mi.
2Ọrọ Oluwa si tọ̀ ọ wá wipe:
3Kuro nihin, ki o si kọju siha ila-õrun, ki o si fi ara rẹ pamọ nibi odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.
4Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ.
5O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.
6Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na.
7O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.
Elija ati Opó kan, ará Sarefati
8Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe,
9Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ.
10On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu.
11Bi o si ti nlọ bù u wá, o ke si i, o si wipe, Jọ̃, mu okele onjẹ diẹ fun mi wá lọwọ rẹ.
12On si wipe, Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, emi kò ni àkara, ṣugbọn ikunwọ iyẹfun ninu ìkoko, ati ororo diẹ ninu kòlobo: si kiyesi i, emi nṣa igi meji jọ, ki emi ki o le wọle lọ, ki emi ki o si peṣe rẹ̀ fun mi, ati fun ọmọ mi, ki awa le jẹ ẹ, ki a si kú.
13Elijah si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; lọ, ki o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi; ṣugbọn ki o tètekọ ṣe àkara kekere kan fun mi ninu rẹ̀ na, ki o si mu u fun mi wá, lẹhin na, ki o ṣe tirẹ ati ti ọmọ rẹ:
14Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: Ikoko iyẹfun na kì yio ṣòfo, bẹni kólobo ororo na kì yio gbẹ, titi di ọjọ ti Oluwa yio rọ̀ òjo si ori ilẹ.
15O si lọ, o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Elijah: ati on ati obinrin na, ati ile rẹ̀ jẹ li ọjọ pupọ̀.
16Ikoko iyẹfun na kò ṣòfo, bẹ̃ni kólobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Elijah sọ.
17O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni ọmọ obinrin na, iya ile na, ṣe aisàn; aisàn rẹ̀ na si le to bẹ̃, ti kò kù ẹmi ninu rẹ̀.
18On si wi fun Elijah pe, Kili o ṣe mi ṣe ọ, Iwọ enia Ọlọrun? iwọ ha tọ̀ mi wá lati mu ẹ̀ṣẹ mi wá si iranti, ati lati pa mi li ọmọ?
19On si wi fun u pe, Gbé ọmọ rẹ fun mi. Elijah si yọ ọ jade li aiya rẹ̀, o si gbé e lọ si iyara-òke ile nibiti on ngbe, o si tẹ́ ẹ si ori akete tirẹ̀.
20O si kepe OLUWA, o si wipe, OLUWA Ọlọrun mi, iwọ ha mu ibi wá ba opó na pẹlu lọdọ ẹniti emi nṣe atipo, ni pipa ọmọ rẹ̀?
21On si nà ara rẹ̀ lori ọmọde na li ẹrinmẹta, o si kepe Oluwa, o si wipe, Oluwa Ọlọrun mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi ọmọde yi ki o tun padà wá sinu rẹ̀.
22Oluwa si gbọ́ ohùn Elijah; ẹmi ọmọde na si tun padà wá sinu rẹ̀, o si sọji.
23Elijah si mu ọmọde na, o si mu u sọkalẹ lati inu iyara-òke na wá sinu ile, o si fi i le iya rẹ̀ lọwọ: Elijah si wipe, Wò o, ọmọ rẹ yè.
24Obinrin na si wi fun Elijah pe, nisisiyi nipa eyi li emi mọ̀ pe, enia Ọlọrun ni iwọ iṣe, ati pe, ọ̀rọ Oluwa li ẹnu rẹ, otitọ ni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. A. Ọba 17: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.