I. A. Ọba 16

16
1O si ṣe, ọ̀rọ Oluwa tọ Jehu, ọmọ Hanani wá, si Baaṣa wipe,
2Bi o ti ṣepe mo gbé ọ ga lati inu ẽkuru wá, ti mo si ṣe ọ li olori Israeli, enia mi; iwọ si rìn li ọ̀na Jeroboamu, iwọ si ti mu ki Israeli enia mi ki o ṣẹ̀, lati fi ẹ̀ṣẹ wọn mu mi binu;
3Kiyesi i, emi o mu iran Baaṣa, ati iran ile rẹ̀ kuro; emi o si ṣe ile rẹ̀ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati.
4Ẹni Baaṣa ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ; ati ẹni rẹ̀ ti o kú ni oko li ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ.
5Ati iyokù iṣe Baaṣa, ati ohun ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
6Baaṣa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Tirsa: Ela, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
7Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a.
Ela, Ọba Israẹli
8Li ọdun kẹrindilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Tirsa li ọdun meji.
9Ati iranṣẹ rẹ̀ Simri, olori idaji kẹkẹ́ rẹ̀, dìtẹ rẹ̀, nigbati o ti wà ni Tirsa, o si mu amupara ni ile Arsa, iriju ile rẹ̀ ni Tirsa.
10Simri si wọle o si kọlù u, o si pa a, li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, o si jọba ni ipò rẹ̀.
11O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀.
12Bayi ni Simri pa gbogbo ile Baaṣa run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ si Baaṣa nipa ọwọ́ Jehu woli,
13Nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ Baaṣa, ati Ela, ọmọ rẹ̀, nipa eyiti nwọn ṣẹ̀, ati nipa eyiti nwọn mu Israeli ṣẹ̀, ni fifi ohun-asán wọn wọnnì mu ki Oluwa, Ọlọrun Israeli binu.
14Ati iyokù iṣe Ela, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Simiri, Ọba Israẹli
15Li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Simri jọba ijọ meje ni Tirsa. Awọn enia si do tì Gibbetoni, ti awọn ara Filistia.
16Awọn enia ti o dotì gbọ́ wipe, Simri ditẹ̀ o si ti pa ọba pẹlu: nitorina gbogbo Israeli fi Omri, olori ogun, jẹ ọba lori Israeli li ọjọ na ni ibudo.
17Omri si goke lati Gibbetoni lọ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, nwọn si do tì Tirsa.
18O si ṣe, nigbati Simri mọ̀ pe a gba ilu, o wọ inu ãfin ile ọba lọ, o si tẹ iná bọ ile ọba lori ara rẹ̀, o si kú.
19Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀.
20Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
Omiri, Ọba Israẹli
21Nigbana li awọn enia Israeli da meji; apakan awọn enia ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin, lati fi i jọba, apakan si ntọ̀ Omri lẹhin.
22Ṣugbọn awọn enia ti ntọ̀ Omri lẹhin bori awọn ti ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin: bẹ̃ni Tibni kú, Omri si jọba.
23Li ọdun kọkanlelọgbọn Asa, ọba Juda, ni Omri bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli fun ọdun mejila: ọdun mẹfa li o jọba ni Tirsa.
24O si rà oke Samaria lọwọ Semeri ni talenti meji fadaka, o si tẹdo lori oke na, o si pe orukọ ilu na ti o tẹ̀do ni Samaria nipa orukọ Semeri, oluwa oke Samaria.
25Ṣugbọn Omri ṣe buburu li oju Oluwa, o si ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o wà ṣãju rẹ̀.
26Nitori ti o rìn ni gbogbo ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀, lati fi ohun-asán wọn wọnni mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu.
27Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?
28Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Ahabu Ọba Israẹli
29Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun,
30Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ.
31O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ,
32O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria.
33Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu.
34Li ọjọ rẹ̀ ni Hieli, ara Beteli, kọ́ Jeriko: o fi ipilẹ rẹ̀ le ilẹ ni Abiramu, akọbi rẹ̀, o si gbé awọn ilẹkun ibode rẹ̀ kọ́ ni Segubu abikẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Joṣua, ọmọ Nuni sọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. A. Ọba 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀