I. Kor 8:1-13

I. Kor 8:1-13 YBCV

ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro. Bi ẹnikan ba si rò pe on mọ̀ ohun kan, kò ti imọ̀ bi o ti yẹ ti iba mọ̀. Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ Ọlọrun, oluwarẹ̀ li o di mimọ̀ fun u. Nitorina niti jijẹ awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe ohun asan li oriṣa li aiye, ati pe kò si Ọlọrun miran bikoṣe ọkanṣoṣo. Nitoripe bi awọn ti a npè li ọlọrun tilẹ wà, iba ṣe li ọrun tabi li aiye (gẹgẹ bi ọ̀pọ ọlọrun ti wà ati ọ̀pọ oluwa,) Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀. Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́. Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera. Nitoripe bi ẹnikan ba ri ti iwọ ti o ni ìmọ ba joko tì onjẹ ni ile oriṣa, bi on ba ṣe alailera, ọkan rẹ̀ kì yio ha duro lati mã jẹ nkan wọnni ti a fi rubọ si oriṣa? Ati nipa ìmọ rẹ li alailera arakunrin, nitori ẹniti Kristi ṣe kú, yio fi ṣegbé? Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣẹ̀ si awọn arakunrin bẹ̃, ti ẹ si npa ọkàn wọn ti iṣe ailera lara, ẹnyin nṣẹ̀ si Kristi. Nitorina, bi onjẹ ba mu arakunrin mi kọsẹ̀, emi kì yio si jẹ ẹran mọ́ titi lai, ki emi má bà mu arakunrin mi kọsẹ̀.