I. Kor 8:1-13

I. Kor 8:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro. Bi ẹnikan ba si rò pe on mọ̀ ohun kan, kò ti imọ̀ bi o ti yẹ ti iba mọ̀. Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ Ọlọrun, oluwarẹ̀ li o di mimọ̀ fun u. Nitorina niti jijẹ awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe ohun asan li oriṣa li aiye, ati pe kò si Ọlọrun miran bikoṣe ọkanṣoṣo. Nitoripe bi awọn ti a npè li ọlọrun tilẹ wà, iba ṣe li ọrun tabi li aiye (gẹgẹ bi ọ̀pọ ọlọrun ti wà ati ọ̀pọ oluwa,) Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀. Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́. Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera. Nitoripe bi ẹnikan ba ri ti iwọ ti o ni ìmọ ba joko tì onjẹ ni ile oriṣa, bi on ba ṣe alailera, ọkan rẹ̀ kì yio ha duro lati mã jẹ nkan wọnni ti a fi rubọ si oriṣa? Ati nipa ìmọ rẹ li alailera arakunrin, nitori ẹniti Kristi ṣe kú, yio fi ṣegbé? Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣẹ̀ si awọn arakunrin bẹ̃, ti ẹ si npa ọkàn wọn ti iṣe ailera lara, ẹnyin nṣẹ̀ si Kristi. Nitorina, bi onjẹ ba mu arakunrin mi kọsẹ̀, emi kì yio si jẹ ẹran mọ́ titi lai, ki emi má bà mu arakunrin mi kọsẹ̀.

I. Kor 8:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa. A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn irú ìmọ̀ yìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun mọ nǹkankan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì mọ̀ tó bí ó ti yẹ. Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn Ọlọrun, òun ni Ọlọrun mọ̀ ní ẹni tirẹ̀. Nítorí náà nípa oúnjẹ tí a fi rúbọ fún oriṣa, a mọ̀ pé oriṣa kò jẹ́ nǹkankan ninu ayé. Ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi ọ̀kan ṣoṣo. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí à ń pè ní oriṣa wà, ìbáà ṣe ní ọ̀run tabi ní ayé, gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti pọ̀, tí “àwọn oluwa” tún pọ̀, ṣugbọn ní tiwa, Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba, lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá, ati lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ń lọ. Oluwa kan ni ó wà. Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a dá gbogbo nǹkan, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá àwa náà. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní ìmọ̀ yìí. Nítorí àwọn mìíràn wà tí èèwọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà ti mọ́ lára tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé, bí wọn bá jẹ irú oúnjẹ yìí, bí ìgbà tí wọn ń bọ̀rìṣà ni. Nítorí wọn kò ní ẹ̀rí ọkàn tí ó lágbára, jíjẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àbùkù fún wọn. Kì í ṣe oúnjẹ ni yóo mú wa dé iwájú Ọlọrun. Bí a kò bá jẹ, kò bù wá kù, bí a bá sì jẹ, kò mú kí á sàn ju bí a ti rí tẹ́lẹ̀ lọ. Ṣugbọn ẹ ṣọ́ra kí òmìnira yín má di ohun tí yóo gbé àwọn aláìlera ṣubú. Nítorí bí ẹnìkan tí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ kò bá lágbára bá rí ìwọ tí o ní ìmọ̀ tí ò ń jẹun ní ilé oriṣa, ǹjẹ́ òun náà kò ní fi ìgboyà wọ inú ilé oriṣa lọ jẹun? Àyọrísí rẹ̀ ni pé ìmọ̀ tìrẹ mú ìparun bá ẹni tí ó jẹ́ aláìlera, arakunrin tí Kristi ti ìtorí tirẹ̀ kú. Ẹ̀ ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí àwọn arakunrin yín tí ó jẹ́ aláìlera, ẹ̀ ń dá ọgbẹ́ sí ọkàn wọn, ẹ sì ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi. Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni yóo bá gbé arakunrin mi ṣubú, n kò ní jẹ ẹran mọ́ laelae, kí n má baà ṣe ohun tí yóo gbé arakunrin mi ṣubú.

I. Kor 8:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ìsinsin yìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀. Imọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní gbé ni ró. Bí ẹnikẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí Ọlọ́run mọ. Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèkéé mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́. Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ. Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà? Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún. Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ. Nítorí nà án, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yóò sì jẹ ẹran mọ́ títí láé, kí èmi má ba à mú arákùnrin mi kọsẹ̀.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa