1 Kọrinti 8

8
Oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà
1 Ní ìsinsin yìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀. Imọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní gbé ni ró. 2 Bí ẹnikẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀. 3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí Ọlọ́run mọ.
4 Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèkéé mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). 6 Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.
7 Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́. 8 Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.
9 Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. 10Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà? 11 Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún. 12 Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ. 13 Nítorí nà án, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yóò sì jẹ ẹran mọ́ títí láé, kí èmi má ba à mú arákùnrin mi kọsẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

1 Kọrinti 8: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa