I. Kor 10:14-33

I. Kor 10:14-33 YBCV

Nitorina, ẹnyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa. Emi nsọ̀rọ bi ẹnipe fun ọlọgbọn; ẹ gbà eyiti mo wi rò. Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe? Nitoripe awa ti iṣe ọ̀pọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitoripe gbogbo wa li o jumọ npin ninu akara kan nì. Ẹ wo Israeli nipa ti ara: awọn ti njẹ ohun ẹbọ, nwọn ki ha iṣe alabapin pẹpẹ? Njẹ kini mo nwi? pe, ohun ti a fi rubọ si oriṣa jẹ nkan, tabi pe oriṣa jẹ nkan? Ṣugbọn ohun ti mo nwi nipe, ohun ti awọn Keferi fi nrubọ, nwọn fi nrubọ si awọn ẹ̃mi èṣu, kì si iṣe si Ọlọrun: emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ba awọn ẹmi èṣu ṣe ajọpin. Ẹnyin kò le mu ago Oluwa ati ago awọn ẹmi èṣu: ẹnyin kò le ṣe ajọpin ni tabili Oluwa, ati ni tabili awọn ẹmi èṣu. Awa ha nmu Oluwa jowú bi? awa ha li agbara jù u lọ? Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró. Ki ẹnikẹni máṣe mã wá ti ara rẹ̀, ṣugbọn ki olukuluku mã wá ire ọmọnikeji rẹ̀. Ohunkohun ti a ba ntà li ọjà ni ki ẹ mã jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀. Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn. Ṣugbọn bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, A ti fi eyi ṣẹbọ, ẹ máṣe jẹ ẹ nitori ẹniti o fi hàn nyin, ati nitori ẹri-ọkàn (nitoripe ti Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀): Mo ni, ẹri-ọkàn kì iṣe ti ara rẹ, ṣugbọn ti ẹnikeji rẹ: nitori ẽṣe ti a fi fi ẹri-ọkàn ẹlomiran dá omnira mi lẹjọ? Bi emi bá fi ọpẹ jẹ ẹ, ẽṣe ti a fi nsọ̀rọ mi ni buburu nitori ohun ti emi dupẹ fun? Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun. Ẹ máṣe jẹ́ ohun ikọsẹ, iba ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun: Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.