I. Kor 10
10
Ìkìlọ̀ Nípa Ìbọ̀rìṣà
1NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já;
2Ti a si baptisi gbogbo wọn si Mose ninu awọsanma ati ninu okun;
3Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna;
4Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na.
5Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù.
6Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ.
7Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire.
8Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan.
9Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn.
10Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn.
11Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá.
12Nitorina ẹniti o ba rò pe on duro, ki o kiyesara, ki o má ba ṣubu.
13Kò si idanwò kan ti o ti ibá nyin, bikoṣe irú eyiti o mọ niwọn fun enia: ṣugbọn olododo li Ọlọrun, ẹniti kì yio jẹ ki a dan nyin wò jù bi ẹnyin ti le gbà; ṣugbọn ti yio si ṣe ọna atiyọ pẹlu ninu idanwò na, ki ẹnyin ki o ba le gbà a.
14Nitorina, ẹnyin olufẹ mi, ẹ sá fun ibọriṣa.
15Emi nsọ̀rọ bi ẹnipe fun ọlọgbọn; ẹ gbà eyiti mo wi rò.
16Ago ibukún ti awa nsure si, ìdapọ ẹ̀jẹ Kristi kọ́ iṣe? Akara ti awa mbù, ìdapọ ara Kristi kọ́ iṣe?
17Nitoripe awa ti iṣe ọ̀pọlọpọ jasi akara kan, ara kan: nitoripe gbogbo wa li o jumọ npin ninu akara kan nì.
18Ẹ wo Israeli nipa ti ara: awọn ti njẹ ohun ẹbọ, nwọn ki ha iṣe alabapin pẹpẹ?
19Njẹ kini mo nwi? pe, ohun ti a fi rubọ si oriṣa jẹ nkan, tabi pe oriṣa jẹ nkan?
20Ṣugbọn ohun ti mo nwi nipe, ohun ti awọn Keferi fi nrubọ, nwọn fi nrubọ si awọn ẹ̃mi èṣu, kì si iṣe si Ọlọrun: emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ba awọn ẹmi èṣu ṣe ajọpin.
21Ẹnyin kò le mu ago Oluwa ati ago awọn ẹmi èṣu: ẹnyin kò le ṣe ajọpin ni tabili Oluwa, ati ni tabili awọn ẹmi èṣu.
22Awa ha nmu Oluwa jowú bi? awa ha li agbara jù u lọ?
Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun
23Ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn ki iṣe ohun gbogbo li o li ere; ohun gbogbo li o yẹ fun mi, ṣugbọn kì iṣe ohun gbogbo ni igbé-ni-ró.
24Ki ẹnikẹni máṣe mã wá ti ara rẹ̀, ṣugbọn ki olukuluku mã wá ire ọmọnikeji rẹ̀.
25Ohunkohun ti a ba ntà li ọjà ni ki ẹ mã jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn.
26Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀.
27Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn.
28Ṣugbọn bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, A ti fi eyi ṣẹbọ, ẹ máṣe jẹ ẹ nitori ẹniti o fi hàn nyin, ati nitori ẹri-ọkàn (nitoripe ti Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀):
29Mo ni, ẹri-ọkàn kì iṣe ti ara rẹ, ṣugbọn ti ẹnikeji rẹ: nitori ẽṣe ti a fi fi ẹri-ọkàn ẹlomiran dá omnira mi lẹjọ?
30Bi emi bá fi ọpẹ jẹ ẹ, ẽṣe ti a fi nsọ̀rọ mi ni buburu nitori ohun ti emi dupẹ fun?
31Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun.
32Ẹ máṣe jẹ́ ohun ikọsẹ, iba ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun:
33Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Kor 10: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.