I. Kor 10:1-11

I. Kor 10:1-11 YBCV

NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já; Ti a si baptisi gbogbo wọn si Mose ninu awọsanma ati ninu okun; Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna; Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na. Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù. Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn. Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá.