I. Kro 12

12
Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ Jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Dafidi Ọba láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini
1WỌNYI si li awọn ti o tọ̀ Dafidi wá si Siklagi, nigbati o fi ara rẹ̀ pamọ, nitori Saulu ọmọ Kiṣi: awọn wọnyi si wà ninu awọn akọni ti nṣe oluranlọwọ ogun na.
2Nwọn le tafa, nwọn si le fi ọwọ ọtún ati ọwọ ọ̀si sọ okuta, ati fi ọrun tafa, ani ninu awọn arakunrin Saulu ti Benjamini.
3Ahieseri ni olori, ati Joaṣi, awọn ọmọ Ṣemaa ara Gibea; ati Jesieli ati Peleti, awọn ọmọ Asmafeti; ati Beraka, ati Jehu ara Anatoti,
4Ati Ismaiah ara Gibeoni, akọni ninu awọn ọgbọ̀n, ati lori ọgbọ̀n (enia) ati Jeremiah, ati Jahasieli, ati Johanani, ati Josabadi ara Gedera.
5Elusai ati Jeremoti, ati Bealiah, ati Ṣemariah, ati Ṣefatiah ara Harofi,
6Elkana, ati Jesiah, ati Asareelti ati Joeseri, ati Jaṣobeamu, awọn ara Kora,
7Ati Joela, ati Sebadiah, awọn ọmọ Jerohamu ti Gedori.
Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Gadi
8Ati ninu awọn ara Gadi, awọn ọkunrin akọni kan ya ara wọn sọdọ Dafidi ninu iho ni iju, awọn ọkunrin ogun ti o yẹ fun ija ti o le di asà on ọ̀kọ mu, oju awọn ẹniti o dabi oju kiniun, nwọn si yara bi agbọnrin lori awọn òke nla;
9Eseri ekini, Obadiah ekeji, Eliobu ẹkẹta,
10Miṣmanna ẹkẹrin, Jeremiah ẹkarun,
11Attai ẹkẹfa, Elieli ekeje,
12Johanani ẹkẹjọ, Elsabadi ẹkẹsan,
13Jeremiah ẹkẹwa, Makbanai ẹkọkanla.
14Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gadi, awọn olori ogun: ẹniti o kere jù to fun ọgọrun enia, ati ẹniti o pọ̀ju to fun ẹgbẹrun.
15Wọnyi li awọn ti o gòke odò Jordani li oṣù ekini, nigbati o kún bò gbogbo bèbe rẹ̀; nwọn si le gbogbo awọn ti o wà li afonifoji ninu ila-õrùn, ati niha iwọ-õrùn.
Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Bẹnjamini ati Ẹ̀yà Juda
16Ninu awọn ọmọ Benjamini ati Juda si tọ Dafidi wá lori òke.
17Dafidi si jade lọ ipade wọn, o si dahun o si wi fun wọn pe, Bi o ba ṣepe ẹnyin tọ̀ mi wá li alafia lati ràn mi lọwọ, ọkàn mi yio ṣọkan pẹlu nyin: ṣugbọn bi o ba ṣepe ẹnyin wá lati fi mi hàn fun awọn ọta mi, nigbati ẹbi kò si lọwọ mi, ki Ọlọrun awọn baba wa ki o wò o, ki o si ṣe idajọ.
18Nigbana ni ẹmi bà lé Amasai, ti iṣe olori awọn ọgbọn na, wipe, Tirẹ li awa, Dafidi, tirẹ li a si nṣe, iwọ ọmọ Jesse: alafia! alafia ni fun ọ! alafia si ni fun awọn oluranlọwọ rẹ; nitori Ọlọrun rẹ ni nràn ọ lọwọ. Dafidi si gbà wọn, o si fi wọn jẹ olori ẹgbẹ-ogun.
Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dafidi láti Inú Ẹ̀yà Manase
19Ninu ẹyà Manasse si ya si ọdọ Dafidi, nigbati o ba awọn ara Filistia wá lati ba Saulu jagun, ṣugbọn nwọn kò ràn wọn lọwọ: nitori awọn olori awọn ara Filistia, nigbati nwọn gbero, rán a lọ wipe, Ti on ti ori wa ni on o fi pada lọ si ọdọ Saulu oluwa rẹ̀.
20Bi on ti lọ si Siklagi, ninu awọn ẹya Manasse ya si ọdọ rẹ̀, Adna, ati Josabadi, Jediaeli, ati Mikaeli, ati Josabadi ati Elihu, ati Sittai, awọn olori ẹgbẹgbẹrun ti iṣe ti Manasse.
21Nwọn si ràn Dafidi lọwọ si ẹgbẹ ogun na; nitori gbogbo wọn ni akọni enia, nwọn si jẹ olori ninu awọn ọmọ-ogun.
22Nitori li akokò na li ojojumọ ni nwọn ntọ Dafidi wá lati ran a lọwọ, titi o fi di ogun nla, gẹgẹ bi ogun Ọlọrun.
Àwọn Ọmọ Ogun Dafidi
23Eyi ni iye awọn enia na ti o hamọra tan fun ogun, ti nwọn si tọ̀ Dafidi wá si Hebroni, lati pa ijọba Saulu da si ọdọ rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
24Awọn ọmọ Juda ti ngbe asa ati ọ̀kọ, jẹ ẹgbãta enia o le ẹgbẹrin, ti o hamọra tan fun ogun.
25Ninu awọn ọmọ Simeoni, akọni enia fun ogun ẹ̃dẹgbarin o le ọgọrun.
26Ninu awọn ọmọ Lefi, ẹgbãji o le ẹgbẹta.
27Jehoiada olori fun Aaroni, ẹgbẹ̃dogun enia o le ẽdẹgbẹrin si wà pẹlu rẹ̀.
28Ati Sadoku, akọni ọdọmọkunrin, ati ninu ile baba rẹ̀ olori mejilelogun.
29Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu.
30Ati ninu awọn ọmọ Efraimu ẹgbãwa o le ẹgbẹrin, akọni ọkunrin, enia olorukọ ni nwọn ni ile baba wọn.
31Ati àbọ ẹ̀ya Manasse ẹgbãsan, ti a yan nipa orukọ, lati lọ fi Dafidi jẹ ọba.
32Ati ninu awọn ọmọ Issakari, ti o ni oye akoko, lati mọ̀ ohun ti Israeli iba ma ṣe; olori wọn jẹ igba; ati gbogbo awọn arakunrin wọn mbẹ ni ikawọ wọn.
33Ninu ti Sebuluni, iru awọn ti o jade lọ si ogun ti o mọ̀ ogun iwé, pẹlu gbogbo ohun èlo ogun, ẹgbamẹ̃dọgbọn; ti nwọn kì ifi iye-meji tẹgun.
34Ati ninu ti Naftali ẹgbẹrun olori ogun, ati pẹlu wọn ti awọn ti asa ati ọ̀kọ ẹgbã mejidilogun o le ẹgbẹrun.
35Ati ninu awọn ọmọ Dani ti o mọ̀ ogun iwé, ẹgbã mẹtala o le ẹgbẹta.
36Ati ninu ti Aṣeri, iru awọn ti njade lọ si ogun, ti o mọ̀ ogun iwé, ọkẹ meji.
37Ati li apa keji odò Jordani, ninu ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati abọ ẹya Manasse, pẹlu gbogbo onirũru ohun elo ogun fun ogun ọ̀kọ, ọkẹ mẹfa.
38Gbogbo awọn ọkunrin ogun wọnyi ti nwọn mọ̀ bi a iti itẹ ogun, nwọn fi ọkàn pipe wá si Hebroni, lati fi Dafidi jọba lori Israeli: gbogbo awọn iyokù ninu Israeli si jẹ oninu kan pẹlu lati fi Dafidi jẹ ọba.
39Nibẹ, ni nwọn si wà pẹlu Dafidi ni ijọ mẹta, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nitoriti awọn ará wọn ti pèse fun wọn.
40Pẹlupẹlu awọn ti o sunmọ wọn, ani titi de ọdọ Issakari, ati Sebuluni, ati Naftali, mu akara wá lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ibakasiẹ, ati lori ibãka, ati lori malu, ani onjẹ ti iyẹfun, eso ọ̀pọtọ, ati eso àjara gbigbẹ, ati ọti-waini, ati ororo, ati malu, ati agutan li ọ̀pọlọpọ: nitori ti ayọ̀ wà ni Israeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa