I. Kro 13

13
A Gbé Àpótí Majẹmu kúrò ní Kiriati Jearimu
(II. Sam 6:1-11)
1DAFIDI si ba awọn olori ogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun ati olukuluku olori gbèro.
2Dafidi si wi fun gbogbo ijọ Israeli pe, Bi o ba dara loju nyin, bi o ba si ti ọwọ Oluwa Ọlọrun wa wá, jẹ ki a ranṣẹ kiri sọdọ awọn arakunrin wa ni ibi gbogbo, ti o kù ni gbogbo ilẹ Israeli, ati pẹlu wọn si alufa ati awọn ọmọ Lefi ti mbẹ ni ilu agbegbe wọn, ki nwọn ki o le ko ara wọn jọ sọdọ wa:
3Ẹ jẹ ki a si tun mu apoti ẹri Ọlọrun wa wa si ọdọ wa: nitoriti awa kò ṣafẹri rẹ̀ li ọjọ Saulu.
4Gbogbo ijọ na si wipe, ẹ jẹ ki a ṣe bẹ̃: nitori ti nkan na tọ loju gbogbo enia.
5Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá.
6Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun.
7Nwọn si gbé apoti ẹri Ọlọrun ka kẹkẹ́ titun lati inu ile Abinadabu wá, ati Ussa ati Ahio ntọ́ kẹkẹ́ na.
8Ati Dafidi ati gbogbo Israeli fi gbogbo agbara wọn ṣire niwaju Ọlọrun, pẹlu orin, ati pẹlu duru, ati pẹlu psalteri, ati pẹlu timbreli, ati pẹlu simbali, ati pẹlu ipè.
9Nigbati nwọn si de ilẹ ipaka Kidroni, Ussa nà ọwọ rẹ̀ lati di apoti ẹri na mu; nitoriti awọn malu kọsẹ.
10Ibinu Oluwa si ru si Ussa, o si lù, nibẹ li o si kú niwaju Ọlọrun.
11Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni.
12Dafidi si bẹ̀ru Ọlọrun li ọjọ na wipe, Emi o ha ṣe mu apoti ẹri Ọlọrun wá sọdọ mi?
13Bẹ̃ni Dafidi kò mu apoti ẹri na bọ̀ si ọdọ ara rẹ̀ si ilu Dafidi, ṣugbọn o gbé e ya si ile Obed-Edomu ara Gitti.
14Apoti ẹri Ọlọrun si ba awọn ara ile Obed-Edomu gbe ni ile rẹ̀ li oṣu mẹta. Oluwa si bukún ile Obed-Edomu ati ohun gbogbo ti o ni.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kro 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀