SEFANAYA 3

3
Ẹ̀ṣẹ̀ Jerusalẹmu ati Ìràpadà Rẹ̀
1Ìwọ ìlú ọlọ̀tẹ̀, o gbé! Ìlú oníbàjẹ́ ati aninilára. 2Ìlú tí kò gba ìmọ̀ràn ati ìbáwí, tí kò gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí kò sì súnmọ́ Ọlọrun rẹ̀. 3Àwọn olóyè rẹ̀ ní ìwọ̀ra bíi kinniun tí ń bú ramúramù; àwọn onídàájọ́ rẹ̀ dàbí ìkookò tí ń jẹ ní aṣálẹ̀ tí kì í jẹ ẹran tí ó bá pa lájẹṣẹ́kù di ọjọ́ keji. 4Oníwọ̀ra ati alaiṣootọ eniyan ni àwọn wolii rẹ̀, àwọn alufaa rẹ̀ sì ti sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́, wọ́n yí òfin Ọlọrun po fún anfaani ara wọn. 5Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ.
6OLUWA wí pé: “Mo ti pa àwọn orílẹ̀-èdè run; ilé-ìṣọ́ wọn sì ti di àlàpà; mo ti ba àwọn ìgboro wọn jẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè rìn níbẹ̀; àwọn ìlú wọn ti di ahoro, láìsí olùgbé kankan níbẹ̀. 7Mo ní, ‘Dájúdájú, wọn óo bẹ̀rù mi, wọn óo gba ìbáwí, wọn óo sì fọkàn sí gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn.’ Ṣugbọn, ń ṣe ni wọ́n ń múra kankan, 8tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Ẹ dúró dè mí di ọjọ́ tí n óo dìde bí ẹlẹ́rìí. Mo ti pinnu láti kó àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ìjọba jọ, láti jẹ́ kí wọn rí ibinu mi, àní ibinu gbígbóná mi; gbogbo ayé ni yóo sì parun nítorí ìrúnú gbígbóná mi.
9“N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan. 10Láti ọ̀nà jíjìn, níkọjá àwọn odò Etiopia, àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan mi tí a fọ́n káàkiri yóo mú ọrẹ ẹbọ wá fún mi.
11“Ní ọjọ́ náà, a kò ní dójútì yín nítorí ohun tí ẹ ṣe, tí ẹ dìtẹ̀ mọ́ mi; nítorí pé n óo yọ àwọn onigbeeraga kúrò láàrin yín, ẹ kò sì ní ṣoríkunkun sí mi mọ́ ní òkè mímọ́ mi. 12Nítorí pé, n óo fi àwọn onírẹ̀lẹ̀ ati aláìlera sílẹ̀ sí ààrin yín, orúkọ èmi OLUWA ni wọn yóo gbẹ́kẹ̀lé. 13Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.”#Ifi 14:5
Orin Ayọ̀
14Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó;
ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi,
ẹ̀yin ará Jerusalẹmu!
15OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò,
ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ.
OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín;
ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́.
16Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé:
“Ẹ má ṣe fòyà;
ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù.
17OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín,
akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni;
yóo láyọ̀ nítorí yín,
yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín,
yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè
18gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.”
OLUWA ní:
“N óo mú ibi kúrò lórí yín,
kí ojú má baà tì yín.
19N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín,
n óo gba àwọn arọ là,
n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ.
N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògo
gbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn.
20N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà,
nígbà tí mo bá ko yín jọ tán:
n óo sọ yín di eniyan pataki
ati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé,
nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín,
Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SEFANAYA 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀