SEFANAYA 2
2
Ìpè sí Ìrònúpìwàdà
1Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ gbìmọ̀ pọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí kò ní ìtìjú. 2Kí á tó fẹ yín dànù, bí ìgbà tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ ìyàngbò káàkiri, kí ibinu Ọlọrun tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìrúnú OLUWA tó dé ba yín. 3Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́; ẹ jẹ́ olódodo, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, bóyá OLUWA a jẹ́ pa yín mọ́ ní ọjọ́ ibinu rẹ̀.
Ìparun tí Yóo Dé Bá Àwọn Ìlú tí Wọ́n Yí Israẹli Ká
4Àwọn eniyan yóo sá kúrò ní ìlú Gasa; ìlú Aṣikeloni yóo dahoro; a óo lé àwọn ará ìlú Aṣidodu jáde lọ́sàn-án gangan, a óo sì tú ìlú Ekironi ká. 5Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé etí òkun, orílẹ̀-èdè Kereti! Ọ̀rọ̀ OLUWA ń ba yín wí, Kenaani, ilẹ̀ àwọn ará Filistia; n óo pa yín run patapata láìku ẹnìkan. 6Ilẹ̀ etí òkun yóo di pápá oko fún àwọn darandaran, ati ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo ti máa jẹko. 7Etí òkun yóo sì di ilẹ̀-ìní fún àwọn ọmọ Juda tí ó kù, níbi tí àwọn ẹran wọn yóo ti máa jẹko, ní alẹ́, wọn yóo sùn sinu àwọn ilé ninu ìlú Aṣikeloni, nítorí OLUWA Ọlọrun wọn yóo wà pẹlu wọn, yóo sì dá ohun ìní wọn pada.#Ais 14:29-31; Jer 47:1-7; Isi 25:15-17; Joẹl 3:4-8; Amos 1:6-8; Sak 9:5-7
8OLUWA ní: “Mo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ àbùkù tí àwọn ará Moabu ń sọ ati bí àwọn ará Amoni tí ń fọ́nnu, bí wọn tí ń fi àwọn eniyan mi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń lérí pé àwọn yóo gba ilẹ̀ wọn. Nítorí náà bí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ti wà láàyè, 9mo búra pé, a óo pa ilẹ̀ Moabu run bí ìlú Sodomu, a óo sì run ilẹ̀ Amoni bí ìlú Gomora, yóo di oko tí ó kún fún igbó ati ihò tí wọ́n ti ń wa iyọ̀, yóo di aṣálẹ̀ títí lae, àwọn eniyan mi tí ó kù yóo kó àwọn ohun ìní wọn tí ó kù.”#Jẹn 19:24
10Wọn yóo sì gba ilẹ̀ wọn, ohun tí yóo dé bá wọn nìyí nítorí ìgbéraga wọn, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn eniyan èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n ń fi wọ́n fọ́nnu. 11OLUWA óo dẹ́rùbà wọ́n, yóo sọ gbogbo oriṣa ilé ayé di òfo, olukuluku eniyan yóo sì máa sin OLUWA ní ààyè rẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè.#a Ais 15:1–16:14; 25:10-12; Jer 48:1-47; Isi 25:8-11; Amos 1:13-15; b Jer 49:1-6; Isi 21:28-32; 25:1-7; Amos 1:13-15
12Ẹ̀yin ará Etiopia, n óo fi idà mi pa yín.#Ais 18:1-7
13Èmi OLUWA yóo dojú ìjà kọ ìhà àríwá, n óo pa ilẹ̀ Asiria run; n óo sọ ìlú Ninefe di ahoro, ilẹ̀ ibẹ̀ yóo sì gbẹ bí aṣálẹ̀. 14Àwọn agbo ẹran yóo dùbúlẹ̀ láàrin rẹ̀, ati àwọn ẹranko ìgbẹ́, àwọn ẹyẹ igún ati òòrẹ̀ yóo sì máa gbé inú olú-ìlú rẹ̀. Ẹyẹ òwìwí yóo máa dún lójú fèrèsé, ẹyẹ ìwò yóo máa ké ní ibi ìpakà wọn tí yóo dahoro; igi kedari rẹ̀ yóo sì ṣòfò. 15Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìlú tí ó jókòó láìléwu, tí ń fọ́nnu wí pé, “Kò sí ẹlòmíràn mọ́, àfi èmi nìkan.” Wá wò ó, ó ti dahoro, ó ti di ibùgbé fún àwọn ẹranko burúkú! Gbogbo àwọn tí wọn ń gba ibẹ̀ kọjá ń pòṣé, wọ́n sì ń mi orí wọn.#Ais 10:5-34; 14:24-27; Neh 1:1–3:19
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SEFANAYA 2: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010