O ti kó sí mi lẹ́mìí, arabinrin mi, iyawo mi,
ẹ̀ẹ̀kan náà tí o ti ṣíjú wò mí,
pẹlu nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn rẹ,
ni o ti kó sí mi lórí.
Ìfẹ́ rẹ ti dùn tó! Arabinrin mi, iyawo mi,
ìfẹ́ rẹ dùn ju waini lọ.
Òróró ìkunra rẹ dára ju turari-kí-turari lọ.
Oyin ní ń kán ní ètè rẹ, iyawo mi,
wàrà ati oyin wà lábẹ́ ahọ́n rẹ,
òórùn dídùn aṣọ rẹ dàbí òórùn Lẹbanoni.
Arabinrin mi dàbí ọgbà tí a ti ti ìlẹ̀kùn rẹ̀.
Ọgbà tí a tì ni iyawo mi;
àní orísun omi tí a tì ni ọ́.
Àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ tí ń sọ dàbí ọgbà pomegiranate,
tí ó kún fún èso tí ó dára jùlọ,
àwọn bíi igi hena ati nadi;
igi nadi ati Safironi, Kalamusi ati Sinamoni,
pẹlu oríṣìíríṣìí igi turari,
igi òjíá, ati ti aloe,
ati àwọn ojúlówó turari tí òórùn wọn dára jùlọ.
Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́,
kànga omi tútù,
àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni.
Dìde, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà àríwá,
máa bọ̀, ìwọ afẹ́fẹ́ ìhà gúsù!
Fẹ́ sórí ọgbà mi,
kí òórùn dídùn rẹ̀ lè tàn káàkiri.
Kí olùfẹ́ mi wá sinu ọgbà rẹ̀,
kí ó sì jẹ èso tí ó bá dára jùlọ.