ROMU 3:20-26

ROMU 3:20-26 YCE

Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe. Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre.